Foluke Daramola Salako- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa

Oríṣun àwòrán, @foluke Daramola
Gbajugbja osere to tun ni ajọ to fi maa n pese iranlọwọ fun awọn agba ọjẹ osere to nilo re, Foluke Daramola Salako tun ti pariwo sita lori agba osere miran.
Loju opo instagram rẹ ni Foluke ti kigbe pe ara agba ọjẹ osere ni Iyabo Oko ko ya lati nkan bii ọdun marun un sẹyin.

Oríṣun àwòrán, @Foluke Daramola
O ni ẹbi, awọn ọmọ ati PARA foundation to jẹ ajọ rẹ ti na ọpọlọpọ owo sẹyin.
O ni koda, won ti gbe Iyabo Oko lọ silu oyinbo fun itọju nibi to ti gbadun ko to pada sile loṣu diẹ sẹyin.
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye ṣàlàyé ìdí tó fi jọ́sìn ní C&S Wòlíì Esther Ajayi
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
- Aàrẹ Joe Biden pè fún alàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ lẹ́yìn ogún ọdún tí ìkọlù 9/11 wáyé ní America
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
Foluke Daramola Salako ni bayii, aisan naa ti pada.
O si ti di aarẹ nla si ara Iyabo oko bayii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Foluke Daramola Salako n ke gbajare si awọn ẹlẹyinju aanu lori ọrọ aisan Iyabo Oko bayii pẹlu adura pe awọn ololufẹ ogbontarigi osere naa ko ni fi iru rẹ gba a.
O tun ni Olorun yoo bukun fun gbogbo ẹni to ba dide iranlọwọ fun agba ọjẹ oṣerebinrin naa, Iyabo Oko













