September 11 attacks: Kí ló ṣẹlẹ̀ ní pàtó lọ́jọ́ kọkànlá, oṣù kẹsàn án, ọdún 2001 l’Amẹrika?

Joe biden

Oríṣun àwòrán, @Joe

Aarẹ Joe Biden ti ni ki awọn eniyan ilẹ America ni suuru

O ni ki wọn gba alaafia ati irẹpọ laaye nitori pe eyi lo le mu ki itẹsiwaju ba agbaye.

Ninu fọran fidio ti aarẹ Joe biden to n tukọ ilẹ America gbe sita lo ti sọ eyi lati sami ọjọ malegbagbe naa ni orilẹ-ede America.

O tun gboriyin fun awọn oṣiṣe iṣẹlẹ pajawiri to kopa akinkanju lasiko naa.

Lọjọ Iṣẹgun, ọkọ kọkanla, ọsu Kẹsan an, ọdun 2001, awọn ẹṣin-o-kọku agbesunmọmi ja awọn ọkọ baalu akero ilẹ Amẹrika kan gba, wọn si sọ ori awọn ọkọ naa mọ ile alaja pupọ kan niluu New York, nibi ti ẹgbẹgbẹrun ẹmi ti sọnu.

Ile alaja World Trade Centre ti wọn ju ado oloro lu nilu New York

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ile alaja World Trade Centre ti wọn ju ado oloro lu nilu New York

Wo ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé l'Amẹrika ní 9/11/2001

Ikọlu naa jẹ eyii to gbomi loju eeyan julọ l'Amẹrika ati kaakiri agbaye.

Ki ni wọn doju ija kọ?

Awọn agbesumọmi naa ja ọkọ baalu mẹrin gba ni iha ila oorun Amẹrika lasiko kan naa, wọn si dori awọn baalu ọhun kọ awọn ile nla ni New York ati Washington DC.

Baalu meji dori kọ ile meji ti wọn n pe ni "Twin Towers" to jẹ ti ibi iṣowo lagbaye ni New York.

Eyii to mu ki ina nla sọ lara awọn ile ọhun, ti ọpọlọpọ eeyan si ha sinu rẹ.

Laarin wakati meji, ile naa to jẹ alaja aadọfa (110) da wo.

Baalu kẹta fori sọ iha iwọ oorun Pentagon, to jẹ olu ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ Amẹrika ni Washington.

Nigba ti ọkọ ofurufu kẹrin ja lule ni papa kan niluu Pennsylvania lẹyin ti awọn ero inu rẹ doju ija kọ awọn agbesumọmi naa, eyi ti igbagbọ wa pe o n lọ fori sọ ile ijọba ti wọn n pe ni Capitol ni Washignton DC.

Awọn olugbe ilu New York re e to n sa asala fun ẹmi wọn kuro nibi alapa ile naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn olugbe ilu New York re e to n sa asala fun ẹmi wọn kuro nibi alapa ile naa

Iye eeyan melo lo ba iṣẹlẹ naa lọ?

Apapọ awọn to ku nibi ikọlu na jẹ ẹgbẹrun mẹta din ni mẹtalelogun.

Ẹni to kere ju to ba iṣẹlẹ ọhun lọ ni Christine Lee Hanson, to jẹ ọmọ ọdun meji pere, to ku pẹlu awọn obi rẹ, Peter ati Sue.

Awoku ile alaja pupọ ọhun re e lẹyin ikọlu naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awoku ile alaja pupọ ọhun re e lẹyin ikọlu naa

Nigba ti ẹni to dagba julọ jẹ ẹni ọdun mejilelọgọrin, Robert Norton, toun ti aya rẹ, Jacqueline, ti wọn jọjọ n lọ sibi ayẹyẹ igbeyawo.

Nigba ti baalu akọkọ kọlu ile kinni, nnkan bii ẹgbẹrun mẹtadinlogun eeyan ati irinwo lo wa ninu rẹ, 17,400, ṣugbọn mejidinlogun sa asala.

Awọn eeyan lati orilẹ-ede mẹtadinlọgọrin kaakiri agbaye lo si wa ninu ile naa.

Awọn wo lo ṣe ikọlu ọhun?Awọn ọmọ ikọ alakakiti ẹsin Musulumi kan ti wọn n pe ni al-Qaeda lo pinlẹ ikọlu naa lati orilẹ-ede Afganistan.

Ṣaaju ni al-Qaeda ati adari rẹ, Osama Bin Laden ti kọkọ di ẹbi rogbodiyan to n waye nilẹ awọn Arabu ru ijọba Amẹrika.

Lara awọn alakatakiti ẹsin ọhun jẹ awakọ ofurufu to kẹkọọ gboye nilẹ Amẹrika.

Awọn eeyan mọkandinlogun pere lo ṣe ikọlu naa, lara wọn si ni a ti ri ọmọ orilẹ-ede United Arab Emirates, Saudi Arabia, Egypt ati Lebanon.

Bawo ni Amẹrika ṣe fesi? Laarin oṣu kan ti ikọlu naa waye, Aarẹ George Bush fi awọn ọmọ ogun ṣọwọ si Afganistan lati pa ikọ Taliban run, ki wọn si ṣawari Osama Bin Laden.Ṣugbọn ọdun mẹwaa lẹyin ikọlu naa ni awọn ọmọ ogun Amẹrika to ṣawari Bin Laden ni Pakistan, ti wọn si fopin si aye rẹ, iyẹn lọdun 2011.

Akojọpọ aworan awọn eniyan to ku sinu iṣẹlẹ 9/11 lọdun 2001 re e ni '9/11 Museum' nilu New York

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Akojọpọ aworan awọn eniyan to ku sinu iṣẹlẹ 9/11 lọdun 2001 re e ni '9/11 Museum' nilu New York

Ẹwẹ, ọdun 2003 ni wọn mu ẹni gan to pinlẹ ikọlu naa, iyẹn Khalid Sheikh Mohammad, o ṣi wa ni atimọle ni Guantanamo Bay lati ọdun naa titi di akoko yii fun igbẹjọ.

Ọdun 2021 yii ni awọn ọmọ ogun Amẹrika fi Afganistan silẹ lẹyin ogun ọdun ti wọn ti tẹkọ leti lọ sibẹ, eyii to n mu ibẹru wa sọkan ọpọ eeyan pe yoo yọri si ipadabọ Abija ikọ al-Qaeda.

Atubọtan iṣẹlẹ 9/11

Eto abo ni awọn papakọ ofuru tunbọ lagbara si.

L'Amẹrika, wọn ṣagbekalẹ ileeṣẹ to n ri si eto abo papakọ ofurufu ati ninu ọkọ ofurufu, iyẹn Transportation Security Administration.

Aarin ọdun kan pere ni wọn tun Pentagon kọ, awọn oṣiṣẹ si pada sinu ọọfisi wọn ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2002.

Ni bayii, wọn ti kọ ile mii si ibi ti Twin Tower wa tẹlẹ, orukọ tuntun ti wọn fun ni One World Trade Center, tabi "Freedom Tower."