Yoruba Self Determination: Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ Yorùbá gbẹ́ná wojú Gumi lórí àbẹ̀wò rẹ̀ sí ìlú Sunday Igboho

Agbarijọpọ awọn ẹgbẹ itẹsiwaju ọmọ Yoruba ti bẹnu atẹ lu abẹwo ti Sheikh Gumi ṣe si ilu Igboho ni ipinlẹ Oyo.
Lopin ọsẹ to kọja ni Sheikh Gumi ati awọn ikọ kan lati Ariwa Naijiria lọ si ilu Igboho ti wọn si fi fọnran fidio kan sita nipa abẹwo wọn.
Ilu Igboho ni ilu abinibi gbajugbaja ajafẹtọmọniyan ilẹ Yoruba ni, Sunday Adeyemo ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho.
- Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa Sheik Gumi tó ń dúnà-dúrá pẹ̀lú àwọn agbébọn ní Nàìjírìá
- Ọ̀run àpáàdì ń dúró de gbogbo ẹ̀yin aláìní ìrònúpìwàdà- Fani Kayode sí Gumi
- Alàgbà Gumi, ẹ lọ mèṣọ́nu lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó lè máa ki àwọn agbébọn láyà- Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà
- Kò sí ìgbà tí mo lọ bá àwọn jàǹdùkú nínú igbó tí ìjọba kò mọ̀ si - Sheik Gumi
Ninu fọnran fidio naa Gumi ati Ọjọgbọn Yusuf sọ pe awọn wa ni Igboho nibi ti awọn ti ri tawọn eeyan n gbe igbe alaafia.
Awọn mejeeji ni awọn ko ri idi ti awọn kan bi Sunday Igboho yoo maa pe fun iyapa Naijiria dipo ki awọn eeyan Naijiria gbe pọ pẹlu alaafia.
Ọrọ ti wọn sọ yi lo mu ki agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba sọ pe ero aburu ni Gumi ni lọkan pẹlu abẹwo rẹ to ṣe si ilu Igboho.
Dokita Steven Abioye to gbẹnusọ fawọn ẹgbẹ yi ni awọn iwa fifa ori apa kan da apa kan si yi ko ni ṣiṣẹ nilẹ Yoruba lọtẹ yi.
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun
- Kí ló mú kí gbogbo títì dá páropáro ṣáájú àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo?
- Àjọ DSS fi ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí kan olùrànlọ́wọ́ Sunday Igboho méjì tó kù sí àhámọ́
- Ẹ mú àrídájú jáde pé Igboho ló ni ilé tí DSS kọlù tàbí pé ẹ̀jẹ̀ èèyàn ló wà nílẹ̀ níbẹ̀ lẹ́yìn ìkọlù náà- Malami
- Ìyàwó Igboho gbé owó wá fún mi, mo kọ̀ọ́ nítorí pé kìí ṣe torí owó ni mo fi n gbẹjọ́ rẹ̀ rò
O ni ''Abẹwo Gumi yi si ilu Igboho lọwọ aburu ninu. Iṣesi awọn Fulani to kun fun ète lo n ṣe. Erongba wọn pẹlu abẹwo yi kii ṣe eyi to mọ''
Abioye tẹsiwaju pe ''bayi ti wọn ri pe saa ijọba Buhari ti fẹ tan,wọn n wa ọna tawọn eeyan yoo fi foju daada wo wọn ki aarẹ Fulani mi ba le bọ sipo''
O ni iru etekete bayi ko le e mu awọn ọmọ Yoruba mọ bi tatẹyinwa.
''Ki lo de to fi ṣe pe ilu Igboho ni Gumi lọ ṣe abẹwo si dipo ilu miran?Nitori pe Sunday Igboho gbe orukọ ilu naa ga ni.Gbogbo ọgbọn ti wọn n da la ti mọ pata''














