Buhari Visits Imo: Nínú àṣẹ tí ìjọba àti Ipob, èwo ní yóò ṣẹ lásìkò àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí Imo?

Aworan aarẹ Buhari ati Nnamdi Kanu

Bi ko ba si idiwọ kankan, aarẹ Buhari yoo tẹsiwaju pẹlu abẹwo rẹ si ipinlẹ Imo nibi ti ikọ Ipob ti ni kawọn araalu ma ṣe jade sita.

Ofin gbele rẹ ti ikọ to n pe fun idasilẹ orileede Biafra yi gbe sita jẹ eleyi ti wọn ko ṣẹṣẹ maa pe iru rẹ lagbegbe naa.

Gẹgẹ bi Ipob ti ṣe sọ, awọn ko wa Buhari lagbegbe awọn ati pe araalu ko gbọdọ jade lati wa ṣe ayẹsi aarẹ.

Amọ ṣa ileeṣẹ ọlọpaa ti ni ki awọn to ba fẹ fa wahala kankan ma ṣe jade sita nitori awọn duro ṣẹpẹ lati koju wọn.

Lowurọ ọjọbọ nigba ti akọroyin BBC jade lati wo nkan to n ṣẹlẹ ni ilu Owerri to jẹ olu ilu Imo, niṣe ni gbogbo titi da paro paro.

Ko si lilọ bibọ awọn ọkọ, bẹẹ naa si ni o jabọ pe titi pa lawọn ileẹkọ wa ni agbegbe naa.

Aworan titi to da paroparo
Aworan titi to da paroparo

Lawọn agbegbe kan, awọn ọlọpaa ati ọmọ ogun mi duro wamuwamu ni igbaradi lati gba aarẹ lalejo.

Kini ayẹwo aarẹ Buhari si Imo yi tunmọ si?

Ẹgbẹ ọmọ ilẹ Igbo Ohanaeze Ndi Igbo sọ pe abẹwo yi fi han pe Baba gbogbo Naijiria ni aarẹ Buhari jẹ.

Ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa Oloye Alex Ogbonnia fi sita, o ni ''pẹlu abẹwo yi, aarẹ ti fi han pe baba gbogbo orileede nii ṣe''

O tẹsiwaju pe awọn ni igbagbọ pe abẹwo yi jẹ eyi to lamilaka ti yoo si mu iyipada ba itan igbesi aye ilẹ Igbo ni Naijiria.

Aworan aarẹ Buhari ati Gomina Hope Uzodinma

Oríṣun àwòrán, Facebook/HopeUzodimma01

Ninu ọrọ ti wọn, ijọba ipinlẹ Imo sọ pe abẹwo yi yoo mu idagbasoke ba igbayegbadun ati eto ọrọ aje ipinlẹ naa.

Kọmisana feto iroyin,Declan Emeluba sọ pe aarẹ yoo ṣe ifilọlẹ awọn akanṣe iṣẹ mẹrin kan ni ipinlẹ naa lasiko abẹwo rẹ.

Ipinlẹ Imo jẹ ibi ti olu ileeṣẹ ikọ ESN sodo si.

Lawọn ipinlẹ to wa ni ilẹ Igbo bi Anambra, Enugu ati Imo, awọn alatilẹyin Nnamdi Kanu to n beere idasilẹ orileede Biafra a maa tẹle aṣẹ konileogbele ti Ipob ba fi lelẹ.