El-Rufai: Inú mí dùn bí wọ́n ṣe mú Nnamdi Kanu, yóò kọ́ àwọn yóòkù tí wọ́n fẹ́ pín Naijiria ní ọgbọ́n

El-Rufai

Oríṣun àwòrán, Others

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai ti fesi fun awọn to n bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ṣe gbe Nnamdi Kanu pada wa si Niajiria.

Nnamdi Kanu ni ijọba gbe lati ẹyin odi, lati wa jẹjọ ẹsun iditẹ gbajọba ti wọn fi kan an lẹyin to sa kuro ni Naijiria lasiko igbẹjọ rẹ.

El-Rufai lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC sọ pe, awọn to n fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn ko ri nkan ṣe si ọrọ Boko Haram ati awọn agbẹbọn, amọ ọrọ Nnamdi Kanu ati IPOB lo jẹ wọn logun, ni wọn ko ri ọrọ sọ.

O ni ọrọ Kanu yatọ si ti awọn agbebọn ni ariwa orilẹede Naijiria nitori ''Nnamdi Kanu n pe fun ituka orilẹede Naijiria, ti o si n fa rogbodiyan ati ija ni Naijiria.

O tilẹ pe orilẹede rẹ ni papa awọn ẹranko''.

Àkọlé fídíò, #BBCNigeria2019: Nnamdi Kanu sọrọ lórí àwọn oludije PDP àti APC

''Eyi yatọ si awọn agbebọn to jẹ wi pe ọrọ aje ni ijinigbe jẹ fun wọn, ti kii ṣe pe wọn gbe ogun ti ijọba pe orilẹede Naijiria gbọdọ tuka.''

''Lakọkọ, inu mi dun pe wọn ri Nnamdi Kanu mu nitori ko naani beeli rẹ , to si ko awọn oniduro rẹ si panpẹ''

''Ekeji ni pe, Kanu fẹ tu orilẹede Naijiria ka, eleyii yoo si kọ awọn to fẹ pin orilẹede Naijiria ni ọgbọn wi pe ki wọn sọ ara ṣe.''

''Rara, rara, rara, bi igba ti ẹ n fi iku we oorun tabi ẹ n pe ọsan ni ''apple'' ni ọrọ Kanu ati awọn agbebọn.''

''Adari ikọ ti ijọba ti pe ni agbesunmọmi ni Kanu, amọ awọn agbebọn ko ni adari pato ti eniyan damọ gẹgẹ bi adari awọn agbebọn wọnyii.''

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè

''Bakan naa ni Kanu joko si ibi kan, to n jaye ọlọba, amọ ijọba Naijiria ti n wa Shekau to jẹ olori awọn ikọ Boko Haram fun ọdun mẹwaa, ti wọn ko ti i ri mu nitori inu aginju lo wa to ti n ja ija tirẹ.''

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-Rufai naa wa kesi ẹnikẹni to ba lero wi pe ọrọ awọn agbebọn ju ti Nnamdi Kanu lọ lati bọ si gbangba pẹlu ẹni to jẹ adari awọn agbebọn to n ji awọn eniyan gbe lorilẹede Naijiria.

Amin iyasọtọ kan

Nàíjíríà yóò ṣàlàyé ìdí tó ṣe fi páńpẹ́ òfin gbé Nnamdi Kanu - Ìjọba Gẹ̀ẹ́sì yarí

Ijọba Ilẹ Gẹẹsi ni oun yoo beere alaye ni ọwọ ijọba Naijiria lori idi to se fi panpẹ ọba mu Nnamdi Kanu, to jẹ adari ikọ IPOB to n pe fun ominira ilẹ Biafra.

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Nnamdi Kanu

Adari Ẹka eto iroyin ni ileesẹ asoju Ilẹ Gẹẹsi ni Naijiria, Dean Hurlock lo sọ eyi lasiko ti awọn akọroyin beere igbesẹ ti wọn n gbe lori atimọle Nnamdi Kanu.

Hurlock ni awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ijọba Naijiria lati salaye bi wọn ṣe mu Nnamdi Kanu ati wi pe ṣe ọna ti wọn gba mu ba ofin mu.

Kanu to n jẹjọ iditẹ gba ijọba ati igbesunmọmi ni wọn gbe lọ si iwaju Adajọ Binta Nyako ni ileẹjọ Giga ti Ilu Abuja, lẹyin ọjọ meji ti ọwọ tẹ ni ẹyin odi ti wọn si gbe pada wa si Naijiria.

Ilẹ Gẹẹsi ninu atẹjade ti wọn fi lede ni kii ṣe Ilẹ Gẹẹsi ni ijọba Naijiria ti mu Kanu, to jẹ ọmọ Ilẹ Naijiria ati Ilẹ Gẹẹsi.

Ijọba Ilẹ Gẹẹsi fikun pe, igbẹjọ rẹ gbọdọ tẹle ilana ofin lai fi ẹtanu tabi aibọwọ fun ofin ṣe ohunkohun nitori awọn ti bẹrẹ si ni tọpinpin lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa ni wọn fikun pe awọn yoo pese iranwọ,ti igbẹjọ rẹ ba bẹrẹ ni Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu Keje, ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

IPOB ni ilẹ Kenya ni wọn ti mu Kanu:

Amọ, mọlẹbi Kanu to tun jẹ agbẹnusọ ikọ IPOB, Emma Powerful sọ fun awọn oniroyin pe orilẹede Kenya ni awọn otẹlẹmuyẹ ti mu Kanu, ti wọn si gbe wa si Naijiria.

Nibayii, Nnamdi Kanu wa ni atimọle ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS gẹgẹ bi aṣẹ ilẹ ẹjọ giga ni Naijiria.

Ọdun 2017 lasiko ti igbẹjọ Kanu ṣi n lọ lọwọ lo sakuro ni Naijiria lọ si Ilẹ Gẹẹsi, nigba ti awọn ọmọogun Naijiria yabo ile obi rẹ ni agbegbe Afaraukwu, nipinlẹ Abia.