Sunday Igboho; Irọ́ ńlá ní pé mo wà ní àtímólé DSS, ilé mí ní Ibadan ní mo wà

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Igboho ti ni ko si otitọ ninu iroyin ẹlẹjẹ to n lọ kaakiri wi pe Ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti mu oun si atimọle.

Ninu ifọrọwanilẹnu ti agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki se fun loju opo Facebook rẹ, ni Sunday Igboho ti bu ẹnu atẹ lu iroyin ẹlẹjẹ ọhun.

Iroyin naa ko si ṣẹyin bi awọn ikọ ọtẹlẹmuye DSS ṣe kọlu ile Sunday Igboho, eyi to mu ẹmi meji lọ, ti ọpọ dukia si bajẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ rẹ, Sunday Igboho ni inu ile oun nilu Ibadan ni oun wa, agbofinro kankan ko si wa gbe oun .

''Ẹkaalẹ gbogbo ẹyin ololufẹ mi kaakiri agbalaaye, orukọ mi ni Sunday Igboho, irọ ni pe mo wa ni panpẹ DSS''

Itakurọsọ pẹlu Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Koiki Media

Ọjọ oni jẹ Ọjọ Keji, Osu Keje, ọdun 2021. Mo ti n gbọ iroyin pe DSS ti mu Sunday Igboho, Emi ko si ni Guru o, mo wa ni ile mi ni Ibadan.''

Ibi ti Sunday Igboho pari ọrọ rẹ si niyii, ki Koiki to ma a ba eto rẹ lọ.

Bakan naa ni Sunday Igboho ati awọn alatilẹyin rẹ lori idasilẹ Yoruba Nation ti ni, ko si ohun ti yoo yẹ iwọde ti wọn fẹ ṣe ni ilu Eko ni Ọjọ Kẹta, Osu Keje, ọdun 2021.