Baba Ijesha: Princess ní òjú gba òun tì fún Iya Rainbow

Gbajugbaja apanilẹrin ati oṣere Nollywood, Princess ti bu ẹnu atẹ lu gbajugbaja oṣere, Idowu Philips ti gbogbo eniyan mọ si Mama Rainbow, lori ọrọ to sọ nipa Baba Ijesha.
Ohun to da ija silẹ laarin Mama Rainbow ati Princess ni ọrọ ti Mama Rainbow sọ lasiko to n ṣe ifọrọwanilẹnuwọ lori ọrọ Baba Ijesha.
Mama Rainbow ni oun bẹ Princess fun odidi ọjọ mẹrin nigba ti ọrọ Baba Ijesha ṣẹlẹ, pe ko mase jẹ ki ọrọ naa di ariwo.
- Ọjọ́ mẹ́rin ni mo fi bẹ Princess pé kí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha má di ẹjọ́ - Iya Rainbow
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Iya Rainbow di ònílé tuntun, ilé méjì ni wọ́n fi ta á lọ́rẹ
- Iya Rainbow jẹ́ gbajúmọ̀, àmọ́ kí lo mọ̀ nípa rẹ̀?
- Àwa kìí jà lásìkò tiwa, ta ló bí ẹ tí wàa máa jà? - Iya Rainbow
- Kíni ẹ mọ̀ nípa Mama Rainbow tó jẹ́ àgbà òṣẹ̀ré tíátà Yoruba?
O ni Princess ko da oun loun nipa ẹbẹ naa, amọ ti ileẹjọ papa gba oniduro Baba Ijesha ni ahamọ lẹyin o rẹyin.
Nigba to n fesi lori ọrọ Mama Rainbow naa ninu fidio ti Princess gbe jade loju ọpọ Instagram rẹ, o salaye bi ọrọ ṣe jẹ laarin oun ati Mama Rainbow nigba ti iṣẹlẹ Baba Ijesha waye.
'Kii ṣe tuntun mọ pe emi ati awọn ẹbi mi nla ina kọja nitori iṣẹlẹ to waye.
Onikaluku lo ni akọsilẹ tirẹ, amọ mo ṣe fidio yii nitori Mama Rainbow, lẹyin ti mo wo ifọrọwanilẹnu ti wọn ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba''
'Oju gba mi ti fun yii nitori ẹ kii ṣe iya rere, inu mi bajẹ nitori mo ri yin gẹgẹ bi iya rere ati ti mo si jẹ ọmọ-ọmọ rere si yin.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
'Ẹ sọ wi pe ẹ bẹ mi fun odidi ọjọ mẹrin, ti mi o si gba ẹbẹ yin, pe bayii wọn ti fi Baba Ijesha silẹ.
Amọ ko si otitọ ninu iroyin pe e pe mi ni ẹẹmẹrin, nitori igba kan pere ni ẹ pe mi.'
'Ẹ ni pe ki n lọ fi Baba Ijesha silẹ ni atimọle ọlọpaa, amọ mi o binu nitori agbalagba niyin, ti mọ si sa gbogbo ipa mi lati salaye ọrọ to ṣẹlẹ fun yin.
Ẹ ni Baba Ijesha lo pe yin fun ara rẹ, wi pe ki ẹ bẹ mi nitori oun hu iwa buruku si mi.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Ẹ sọ wi pe ki n fi adirẹsi ile mi ranṣẹ si yin, amọ ẹ ko wa, lẹyin ọjọ kẹta, ẹ tun pe mi lori aago pe ẹ ri pe ọkan mi ko balẹ, pe mo n sun kun, amọ ẹ ko yoju si mi'
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kí ló dé tí DSS kó bàńtẹ́ òògùn, ba ilé Sunday Igboho jẹ́ lái fara pa?
- "DSS, níbo ni ₦2m àti owó Euro, Dollar àti Pound Sterling tẹ kó nílé mi wà? "
- Sunday Igboho, ìsáǹsá rẹ̀ kò lé sá mọ́ wa lọ́wọ́, mímú lá mú ọ - DSS fọwọ́ gbáyà
- Sunday Igboho ń ṣọ̀fọ̀ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí DSS pa
- À ṣe ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, bí ọlọ́pàá fẹ́, bó kọ̀ - Igun Sunday Igboho
- "Sunday Igboho, Banji Akitoye, ẹ rìn jìnnà sójú pópó Eko fún ìwọ́de Yoruba Nation"
Princess to fi ibinu sọrọ ni pe, ka ni ọmọ Mama Rainbow ni iru iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ si, wọn ko ni ma a ba orukọ oun jẹ kaakiri.'
Princess fikun pe, oun ni igbagbọ pe otitọ ni yoo leke ninu iṣẹlẹ yii ati wi pe ohun gbogbo to sokunkun ni yoo pada han si kedere.
















