Sunday Igboho: Òògùn ìbílẹ̀ ni mo fi n dáàbò bo ara mi, kìí se ìbọn

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, sunday_igboho1/Instagram

Gbajugbaja ajafẹtọ ẹni, Oloye Sunday Igboho ti figbe ta pe awọn osisẹ DSS to wa sile oun ko awọn oku awọn eeyan ti wọn pa lọ.

Sunday Igboho ẹni to fi atẹjade kan sita lati ipasẹ agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki ni irọlẹ ọjọ Ẹti , wa salaye awọn bi ikọlu awọn DSS se waye nile rẹ ati ohun to faa.

Bakan naa ni Igboho mẹnuba pe ilana bi awọn agbofinro se pa awọn oluwọde Endsars logunjọ osu kẹwa, ti wọn si gbe oku wọn lọ, naa ni wọn lo nile oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"To ba jẹ pe ijọba Buhari yege lati pa mi ni, wọn ko ba kede pe awọn ko mọ awọn agbebọn to wa sisẹ ibi naa ni.

O si yẹ ki awujọ agbaye mọ pe aayan ti n lọ lati fi tipa mu awọn eeyan ti wọn ko ninu ile mi lati jẹwọ oun ti wọn ko se ni tipa tipa, eyi to le se akoba fun wọn.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Mo wa fẹ ki awujọ agbaye mọ pe ẹni to n bọwọ fun ofin ni mi , mo si n rọ aarẹ Buhari lati rọ awọn agbofinro rẹ, ki wọn dẹkun irọ pipa nipa mi lati ba orukọ mi jẹ."

DSS kọkọ ba ẹrọ ayaworan to wa nile mi jẹ, ki wọn to bẹrẹ ikọlu wọn

Igboho ti wa n fọwọ sọya pe oun ko mọ ohunkohun nipa awọn ibọn ti ajọ DSS safihan rẹ pe wọn ko ninu ile oun.

O wa n ke si awujọ agbaye pe ko ye wọn pe o see se ko jẹ inu ibudo iko nnkan ijagun pamọ si to wa ni ọọ̀fisi ajọ DSS ni wọn ti ko awọn ibọn ti wọn safihan rẹ jade.

"Boya awọn agbofinro to ya bo ile mi lo dọgbọn ko awọn ibọn naa wa sibẹ ni tabi ko jẹ pe inu ile ti wọn n ko ohun ija pamọ si ni wọn ti ko awọn ibọn naa jade.

Wọn parọ mọ mi ni, eyi si foju pe idi ti wọn se fi oru mọju wa sile mi ree, ti wọn si ba awọn awọn ẹrọ ayaworan mi jẹ, ki wọn to bẹrẹ isẹ.

Ti ko ba jẹ pe wọn ni ete miran, ki lo de ti wọn ko so ẹrọ ayaworan mọra lati maa ya gbogbo bi wọn ti n sisẹ nile mi, bẹrẹ lati igba ti wọn ti wọle.

O si ti foju han pe pẹlu isesi wọn yii, ijọba Buhari setan lati lo ọnakọna fi pa ẹnu araalu mọ."

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson Shomolu Bariga ní 'Restructuring'ti bọ́ aṣọ kò bá Omọyẹ mọ́!

N ko mọwọ-mẹsẹ nipa ibọn ti awọn DSS kede pe wọn ri ninu ile mi

Gbajugbaja ajafẹtọ Yoruba naa tun ti sẹ pe oun kọ ni oun ni awọn ibọn ti awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS se afihan rẹ.

Igboho ni awọn agbofinro naa lo wa sile oun lai mu iwe asẹ lati yẹ ile oun wo wa, gẹgẹ bi ofin ti laa kalẹ, ti wọn si ba awọn dukia oun olowo iyebiye jẹ.

O ni wọn pa awọn eeyan, ti wọn si tun ji ọpọ ohun alumọni ati owo lọ ninu ile oun, eyi ti aworan atawọn fidio rẹ ti wa kaakiri ninu awọn iwe iroyin.

Igboho ni bi aarẹ Buhari se kuna lati dẹkun iwa ọdaran awọn darandaran lo mu ki oun dide lati da si ọrọnaa nitori oun ko ba ti se bẹẹ, ti ijọba ba mọ isẹ rẹ bii isẹ ni.

"Bi mo si se n jija gbara mi ko lọwọ itajẹsilẹ tabi gbigba ẹmi lẹ. Ọna ti mo n gba lati dena iwa ọdaran ni lati le awọn Fulani kuro ni ibuba wọn.

Awọn ileesẹ agbofinro ati ileesẹ aarẹgan si mọ pe n ko tako awọn Fulani to n gbe ni alaafia tabi awọn ẹya miran to wa ni ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria."

Sunday Igboho wa fikun pe lẹyin ọpọ iyanju lati fi tipa pa oun lẹnu mọ, amọ ti ko see se, ni wọn wa ri oun bii ewu nla , ti wọn si n dete lati ba oun ni orukọ jẹ.