Sunday Igboho: Deji Adeyanju bu ẹnu àtẹ́ lú ìkọlù DSS sílé Igboho

Igboho dúpẹ́ tiẹ pé, ìbọn lásan ni Buhari gbé sí ọ nígba kìí ṣe adó olóró- Deji Adeyanju

Oríṣun àwòrán, DSS

Ajàfẹ́tọ ọmọniyan, Deji Adeyanju ti woye pé kò le jẹ́ Sunday Igboho lo ni awọn ibọn ti DSS bá nílé rẹ̀.

Deji Adeyanju fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lójú òpó ìkànsíraẹni ayelujara rẹ̀, to sì bẹnú àtẹ́ lu bi àwọn osisẹ agbofinro ṣe ṣekúpa àwọn ènìyàn méjì nílé Igboho.

Bákan náà ló ní ó yẹ kí Igboho maa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹ́dàá rẹ̀ pé ìbọ̀n ni wọn dẹ sílẹ̀ nílé rẹ̀, kìí ṣe àdó olóró.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ó yẹ́ kí Igboho máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlẹ́dàá rẹ pé ìbọn ni wọ́n gbé wa sílé rẹ̀, kìí ṣe adó olóró"

"Wọn pa ènìyàn méjì nílé Igboho, wọ́n sì ń se bi ẹ ni pé wọ́n kò tilẹ hùwà ọ̀daràn kankan.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Sáájú ni ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹmúyẹ ti sọ pé àwọn ni àwọn lọ sí ilé Sunday Igboho, lẹyin ti wọn ta àwọn kan ta awọn ni olobó pé Sunday Adeyemọ kó nǹkan ìja ogun pamọ sílé.

Bákan náà ni wọ́n fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn pa àwọn ènìyàn méjì nínú àwọn tó dójú ìjà kọ àwọn

Adeyanju ni kò sí ẹni tí ó kọjá òfin pe, ìgbàgbọ́ sì wà pé, àwọn tó kù tí wọ́n kó nílé Sunday Igboho yoo lọ fojú ba ilé ẹjọ́.

Àwọn nǹkan ti wọ́n kéde pé àwọn bá ní ilé Sunday Igboho ni, oníruuru Ibọn, ìwé ìrìna lóríṣirísi, owó dọ́là àti àwọn nǹkan mííràn bi ọkọ̀.