Sunday Igboho: Afenifer ń bèèrè pé ṣé Nàíjíríà ti padà sí sáà oko ẹ̀rú ológun ni?

Alagba Ayo Adebanjo ati ọkọ Sunday Igboho

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lorilẹede Naijiria, Afẹnifẹre ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, DSS ṣe si ile ajijagbara fun ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.

Adele fun Alaga ẹgbẹ Afenifere, Oloye Ayo Adebanjo ni ikọlu ti wọn ṣe si ile Sunday Igboho yii mu ki awọn eniyan ranti nkan ti awọn ọmọ Naijiria la kọja lasiko ijọba Ọgagun Sani Abacha.

Adebanjo ni o ṣe ni laanu pe ikọlu naa fihan bi Naijiria ṣe ti n pada si oko ẹru ati iya aitọ to wọpọ lasiko ijọba Ologun Sani Abacha, ti ẹnikẹni to ba sọrọ tako ijọba yoo foju wina ikọlu lati ọdọ awọn ẹṣọ alaabo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe bi wọn ṣe ṣekọlu si ile Sunday Igboho ko ṣẹyin iṣẹ ijọba apapọ orilẹede Naijiria ati awọn to wa ni ipo adari.

''Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni awọn to wa ṣekọlu naa si Sunday Igboho wọ aṣọ awọn ẹṣọ alaabo lorilẹede Naijiria''

Ile Igboho ti wọn bajẹ

''Bakan naa ni aibikita ẹṣọ alaabo lati wa doola ẹmi awọn eniyan nigba ti iṣẹlẹ naa waye fun wakati mẹta, fihan pe awọn ọlọpaa lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, nitori agọ ọlọpaa yi agbegbe naa ka.''

''Nitori ko si ọlọpaa kankan to wa sibẹ lati wa koju awọn to ṣekọlu naa, eyi to fihan pe ijọba lọwọ ninu iṣẹlẹ naa''

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni eleyii ko yatọ si nkan to n waye lasiko ijọba Ologun ni Naijiria, bi wọn ṣe n fi iya jẹ awọn eniyan lọna aitọ, ti wọn si n ṣekọlu si ẹni to ba sọrọ tako Abacha.

' A ranti bi wọn ṣe fi iya jẹ awọn ogbontagiri ọmọ Yoruba nigba naa bi Ọgagun Alani Akinrinade, Pa Abraham Adesanya, Pa Alfred Rewane ati bẹẹ bẹẹ lọ.'

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

'Iya yii pọ to bẹẹ ti o jasi iku Pa Rewane nigba naa lọhun.'

Ẹgbẹ Afẹnifẹre wa fi asiko yii ke gbajare sita pe, wọn tun ti bẹrẹ si ni ṣe ikọlu si awọn ọmọ Yoruba paapaa awọn to n ja fun ominira ati ẹtọ awọn ọmọ Oduduwa.