Sunday Igboho: Banji Akitoye ní kí àwọn ọmọ Yorùbá bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de níwájú ilé àwọn ọba kọ̀ọ̀kan

Oríṣun àwòrán, Maxwell
Olórí àpapọ̀ ọmọ Yorùbá tó fẹ́ dá dúró, Ìlànà Omo Oodua (IOO) ọjọ̀gbọ́n Banji Akintoye tí sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù tó wáyé ni ilé ajìjàgbara ọmọ Oodua olóyè Sunday Igboho nílùú Ibadan.
Nínú àtẹ̀jáde tí ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye fọwọ́sí, ló ti fẹ̀sùn kàn pé àwọn ọmọogun Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ kan láti ilẹ́ òkèrè, ni ìjọba lò láti ṣe ìkọlù sí ilé Sunday Igboho.
Ó sọ pé àwọn àpànìyàn náà wọ aṣọ sọ́ja, tí wọ́n sì n sọ èdè faranse àti pé wọ́n tún gbé ìyàwó rẹ̀ lọ.
- Ìbọn àti nǹkan ìjagun ni Igboho kó pamọ sílé ló jẹ kí á yabo ilé rẹ̀ - DSS
- Níbo ní Sunday Igboho wà lẹ́yìn ìkọlù síle rẹ̀? Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ń bèèrè
- Àwọn ẹgbẹ́ ajìjàgbara Yoruba fọnmú lórí ìkọlù sílé Sunday Igboho
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Ẹ̀jẹ̀ kúnlẹ̀ nílé Sunday Igboho, ẹ̀mí méjì bọ́ lásìkò tí afurasí Sọ́jà kọlu ilé rẹ̀
- Afurasí ‘Sọ́jà’ kọlu ilé Sunday Igboho lóru mọ́jú, òkú ṣùn, dúkìá bàjẹ́
- Sunday Igboho, ṣe sùúrù díẹ̀ lórí ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko - Olugbon ń lọgun
- Agbébọn yabo ilé Sunday Igboho ní òru mọ́jú
- ''Ẹ ó ríjà Ọba, tí ẹ bá gbìyànjú láti fọ́wọ́ kan Sunday Igboho''
- Ọwọ́ ṣìnkún ọlọ́pàá tẹ Kayode Esuleke, olórí Eléégún l‘Osogbo
Baba Akintoye tún fi kun pé, àwọn agbẹ́bọn náà tún pa ènìyàn méje nílé rẹ̀ tí wọ́n sì gbé òkú ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n jí gbé lọ.
Gẹ́gẹ́ bi àtẹ̀jáde náà ṣe sọ, ó ní ìdáhùn pàjàwírí rèé láti ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ ìlànà ọmọ Oodua sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì:

"Ní aago kan oru lónìí ọjọ́bọ, ọjọ́kini oṣù kejè ọdún 2021.
" Ilé ọkan lára asíwájú nínú ìjàgbàra ọmọ Yoruba ni àwọn agbébọ̀n kọlù"
"Mo fẹ́ sọ fún gbogbo ayé pé ikọlù náà kò ṣẹ̀yìn àwọn ọmọogun Nàìjíríà tí àwọn àti àwọn agbésùmọ̀mí láti ilẹ̀ òkèrè jọ dawọ́pọ̀ ṣiṣẹ"
" Mò n sọ láì fi ti ìbẹ̀rù ṣe, ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ló dide ogun si àwọn àwọn ọmọ Yorùba"
"Láti ìgbà ti a ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí ní à tí ń ṣe gbogbo nǹkan pẹ̀lú àláfíà , gbogbo òfin ìjọba Nàìjíríà àti tí àwọn ilẹ̀ òkèrè ni a tẹ̀lé bí a tilẹ̀ ń wá òmìnira ara wa."
Olóyè Akintolye ni lórúkọ gbogbo ọmọ Yoprùbá , ìkọlù sí ilé Sunday Igboho kìí ṣe èyí tí ó yẹ rárá, kò bá òfin mú ó sì jẹ́ ìwà ìkà.

Akintoye ké pe àwón ọmọ Nàìjíríà nílé àti lẹ́yìn odi láti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn níwájú àwọn ilé ọba ilẹ̀ Yorùba àti níwájú ọ́fíísí United Nation, European Union, ofíísì asọjú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, French àti ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà.
" A sì n fi àsìkò yìí sọ pé ìwọde Yoruba Nation tó yẹ kí ó wéyé lọ́jọ́ Satide ṣì n tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe pinu.












