Sunday Igboho: Wo ìgbà mẹ́rin tí ìkọlù ti wáyé nílé Sunday Igboho

Sunday Igboho ati ọta ibọn

Lẹyin wakati diẹ ti awọn agbebọn kọlu ile ajijagbara fun iran Yoruba, Oloye Sunday Igboho, ibeere ti ọpọ eeyan n beere ni pe nibo ni ajijagbara naa wa?

A ti sọ fun yin saaju pe awọn eeyan kan to mura bii ọmọ ogun yabo ile Igboho nidaji Ọjọbọ, ti wọn si pa eeyan meji, gẹgẹ bi agbẹnusọ rẹ ti wi.

Abẹwo BBC Yoruba si ile naa si fihan pe ẹjẹ wa nilẹ kaakiri, ti ọpọ dukia si bajẹ.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn eeyan ta ba ninu ile naa ko le sọ ibi ti Igboho wa amọ awọn kan ni o ti poora lasiko ti awọn agbbọn naa de sibẹ.

Lẹyin wakati mẹwa ti ikọlu yii ti waye, agbẹnusọ fun Igboho nikan lo n ba araalu sọrọ, ti awọn eeyan si n beere pe ki lo de ti ajijagbara naa ko jade ki awọn ri pe alaafia lo wa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Ẹ fi Ògún búra fún wa láti jà fún ilẹ̀ Yorùbá láì gbé Amotekun sábẹ́ ìjọba

Koda, awọn eeyan to ba BBC sọrọ ni nigba tawọn amookunsika gan sọ ina si ile Sunday Igboho lalakọkọ, funra rẹ lo jade sita lati ba awọn akọroyin sọrọ.

Wọn wa n beere pe ki lo de lọtẹ yii ti awọn ko fi kofiri rẹ, ti ọpọ si n kaya soke pe se alaafia lo wa.

Lero tawọn eeyan mira, wọn ni se lo yẹ ki Igboho jade sawọn eeyan to wa se ikọlu yii, ko si se wọn bii ọsẹ ti n soju gẹgẹ bo se maa n fi ọwọ gbaya.

Bakan naa ni wọn n para poro pe awọn eeyan to ku ati awọn ti wọn ji gbe lọ, ko ba ti wa ninu ewu, ti Igboho ba fiya to tọ jẹ awọn to wa se ikọlu ọhun.

Ọkọ Sunday Igboho ti wọn bajẹ

Igba mẹrin ti wọn ti se ikọlu sile Igboho:

Igba karun ree ti awọn eeyan kan yoo kọlu ile Sunday Igboho nitori wọn ti kọlu ile rẹ nigba mẹrin sẹyin.

Inu ọdun 2021 ta wa yii nikan si ni awọn ikọlu maraarun naa ti waye saaju.

Ibudo Guru Maharaji loju ọna marosẹ Ibadan silu Eko:

Igba akọkọ ti ikọlu yoo waye si Sunday Igboho ni akoko to n lọ silu Eko, lati lọ sile Iba Gani Adams.

Opopona Marosẹ Ibadan silu Eko, niwaju ile Guru Maharaji ni awọn osisẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti da ikọ rẹ duro.

Iroyin to gbalẹ kan nigba naa ni pe awọn DSS naa fẹ gbe Sunday Igboho ni amọ ti awọn onitọun ni ko ri bẹẹ.

Awọn afurasi Sọja

Oríṣun àwòrán, Facebook/Koiki Media

Afurasi Sọja meji wa tọpinpin ile rẹ:

Bakan naa ni iroyin gbode pe awọn afurasi Sọja meji wa tọpinpin ile Sunday Igboho amọ ti awọn ọmọ ẹyin rẹ mu wọn mọlẹ.

Awọn afurasi Sọja naa lo wọ asọ ologun ti wọn si n gun ọkada kọja ni ogunjọ osu kẹta ọdun 2021 ti isẹlẹ naa waye.

Amọ awọn afurasi naa ni awọn n lọ jẹjẹ tawọn ni wọn da awọn duro, ti awọn ko si wa se ohunkohun ninu ile naa.

Lẹyin o rẹyin ni wọn fa awọn afurasi naa le ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo lọwọ, ti ileesẹ ologun si fi ikede sita pe awn ko ni pẹlẹngọ lati mu Igboho tawọn ba setan lati se bẹẹ.

Ile Sunday Igboho to jona

Awọn Janduku sọ ina sile Sunday Igboho:

Awọn janduku kan la gbọ pe wọn ya bo ile akọkọ ti Sunday Igboho kọ si agbegbe Soka nilu Ibadan, amọ kii se ile yii lo n gbe.

Aimọye dukia lo jona ninu ile naa, ti wọn si tun ni awọn agbebọn ọhun gbe kẹẹgi epo pẹtiroolu wa lati sun ile naa ni.

A gbọ pe ọpẹlọpẹ awọn ọmọ ẹyin Igboho to jade ti wọn, tawọn janduku ọhun to gbe ọkọ bọọsi ati ayọkẹlẹ wa, si sa lọ.

Awọn agbofinro mu lẹta wa sile Sunday Igboho:

Igba kẹrin ti ariwo yoo sọ pe wọn se ikọlu sile Sunday Igboho ni akoko ti wọn ni awọn osisẹ agbofinro ko ọkọ bọọsi wa lati fun Igboho ni lẹta kan.

Wọn ni ọga agba ọlọpaa nilẹ yii lo fi lẹta naa ransẹ si amọ tawọn ọmọlẹyin Igboho yari lati gba iwe naa.