Sunday Igboho: A gba Igboho nímọràn láti lọ fa ara rẹ lé Ọlọpàá lọwọ kíá! – DSS

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Ileesẹ ọtẹlumuyẹ Naijiria DSS ti tuṣo loju eegun ọrọ to n lọ lọwọ nípa ikọlu to waye lonii ni ile ajafeto-omoniyan Yoruba nni Sunday Igboho.

Lasiko ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ lalẹ Ọjọbọ, àjọ naa ni looto láwọn ṣe ikolu sí ile Sunday Igboho ti eeyan meji ninu awọn ẹṣọ rẹ sí fara gbọta.

Alukoro ajo naa arakunrin Peter Ifunaya ṣalaye pe loru t'awọn ṣigun lọ sí ilé Igboho nise lawọn ẹṣọ rẹ ṣina ibọn lù awọn ṣugbọn awọn ri meji mu balẹ ninu wọn ti awọn meje mii sí wa ni ikapa awọn.

Ohun ti wọn ba nile Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

O tẹsiwaju pe Igboho fúnra rẹ na papa bora lasiko ikọlu yi ti awọn ko sí ní sinmi titi ti ọwọ yóò fi tẹ.

"A rọ Igboho ati gbogbo awọn to n gbe lẹhin rẹ lati sọ fún un tàbí kí oun gaan alara jọwọ ara rẹ fawọn agbofinro. Ati oun tabi awọn to ku, ko sí ẹni tí o kọja ofin".

Lasiko ti o n ba awọn akọroyin sọrọ, Ifunaya ṣafihan àwọn ibọn ati nkan mii to ni awọn ri gba lọdọ awọn ti ọwọ tẹ ati ninu ile Igboho.

Ibọn atamatase Ak-47 ọta ibọn, iwe irina pasipọọti ati ẹrọ ibanisọrọ alagbeka wa lara nkan to ní awọn ri ni ile rẹ.

Ohun ti wọn ba nile Igboho

Oríṣun àwòrán, DSS

Ẹwẹ, agbẹnusọ Sunday Igboho Koiki ti sọ pe iwọde t'awọn n gbero lati ṣe n'ilu Eko yoo sì tẹsiwaju.

Ninu fónrán fídíò kan to fi sita loju opo Facebook lalẹ ọjọbo ni o ti fi ọrọ yi lede.

Àkọlé fídíò, Soiless Farming: Samson Ogbole ní táwọn irè oko bá fara kan ilẹ̀, ló ń kó àrùn bá wọn