Baba Ijesha: Lola Alao ní òun àti Iyabo Ojo rán agbẹjọ́rò méjì gbìjà Baba Ijesha àmọ́ ibi ni wọn fi su àwọn

Lola Alao

Oríṣun àwòrán, Lola Alao

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awuyewuye lori ọrọ Baba Ijesha lagbo awọn oṣere tiata Yoruba ko ti tan nilẹ patapata pẹlu bi awọn oṣere ṣi tun se n tahun si ara awọn.

Ọkan lara awọn oṣere tiata, Lola Alao naa ti da si ọrọ to n lọ, Bukky Black lo si doju ọrọ tiẹ kọ nitori oko ọrọ ti onitọun sọ si Iyabo Ojo.

Lola tutọ soke o foju gbaa lori fidio ti Bukky Black ṣe eleyii to fi tako Iyabo Ojo lori ọrọ Baba Ijesha.

Lola sọ pe niwaju Ọlọrun ati eniyan, Iyabo ko mọ ohunkohun nipa ọrọ yii rara, o ni oun gan an ni oun pe Iyabo nigba toun gbọ pe awọn ọlọpaa ti mu Baba Ijesha.

''Bukky, ni akọkọ na, mo fẹ ki o mọ pe bi wọn ti gba beeli Baba Ijesha ko tumọ si pe ẹjọ ti pari o.

Àkọlé fídíò, Soiless Farming: Samson Ogbole ní táwọn irè oko bá fara kan ilẹ̀, ló ń kó àrùn bá wọn

Emi fun ra mi ni mo fi agbẹjọro meji ranṣẹ si Baba Ijesha ni agọ ọlọpaa ti wọn ti i mọ lẹyin ti mo ba Iyabo sọrọ tan.

Ẹ ba mi beere lọwọ Ijesha boya ko ri awọn agbẹjọro meji ti mo fi ranṣẹ si i.

Iyabo ko korira Ijesha, ohun to ṣẹlẹ gan an ni Iyabo n sọ nitori iru nkan bayii ti ṣẹlẹ si i ri."

Lola Alao ni oun gan ni oun fi isẹlẹ naa to Yomi Fabiyi ati Iyabo Ojo leti, gẹgẹ bi aburo oun tawọn mejeeji jẹ, ti wọn si dide lati gba Baba Ijesha silẹ nitori awọn lero pe wọn fẹ ba lorukọ jẹ ni.

O ni bi awọn mejeeji si se gbọ ọrọ yii ni wọn dide pe awọn yoo lọ lai jẹ pe ẹnikankan ninu awọn tiẹ mọ ohun ti Baba Ijesha se, to fi de agọ ọlọpaa.

Koda, Lola Alao fidi rẹ mulẹ pe oun n reti Baba Ijesha ko wa ba oun nilu oyinbo ti oun wa lati se sinima kan papọ amọ ti awọn ko ri, to si n ka oun lara pe bawo lo se maa hu iru iwa bayii si oun.

Amọ o ni nigba ti oun pe lati wadi idi ti ko se tii de, ni jẹbẹtẹ gbe ọmọ le oun lọwọ nigba toun gbọ pe o ti wa ni ahamọ ọlọpaa ni Panti.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Koda, Yomi Fabiyi gan bẹrẹ si kọ awọn ọrọ lati gbeja Baba Ijesha, ti oun gan si n se alabapin awọn ọrọ naa loju opo Instagram oun amọ ni kete ti oun mọ idi ọrọ to sẹlẹ, ni oun pa awọn ọrọ naa rẹ.

"Nigba ti Princess fi fidio ranṣẹ, ti emi ati Iyabo wo o tan, ni Iyabo mura pe idajọ ododo gbọdọ ṣẹlẹ lori ọrọ naa.

Bukky, Iyabo ko ba ti sọrọ ti ko ba ṣe fidio ti o fi lede lori ayelujara.

Ṣebi agbalagba ni ẹ, Bukky? Ṣe agbalagba maa n ṣe langbalangba ni?

Bukky, ki ni iwọ ṣe nigba ti wọn mu Baba Ijesha, ṣe bi a jọ wa ni ilu oyinbo ni?

Mo ti n dakẹ lori ọrọ yii tipẹ ṣugbọn ẹri ọkan mi ko jẹ ki n gbadun, jẹjẹ ni Iyabo joko sile rẹ, ẹmi ni mo fi ọrọ Baba Ijesha lọ ọ.

O n dun mi pe emi ni mo ti Iyabo si gbogbo wahala yii.

Awọn adigunjale ti wa sile mi ri ti wọn ji goolu mi atawọn nkan mii, nitori naa ti wọn ba mu ole nibi kan, mo maa n fẹ ki wọn lu daadaa nitori o ti ṣẹlẹ si mi ri.

Àkọlé fídíò, Glorious Twins: Taiwo àti Kehinde Ekundayo ní ọ̀dọ́ ìyá àgbà ní àwọn ti ẹ̀bún orin kíkọ

Bayi naa si lo maa n ri lara Iyabo to ba gbọ nipa ẹnikan to fi tipa ba obinrin lo pọ."

Lola Alao wa koro oju si bi ọpọ eeyan se n sọrọ si Iyabo Ojo lori ayelujara, to si tun gbara ta lori aarin Yomi Fabiyi ati Iyabo Ojo to ti daru bayii nitori ọrọ Baba Ijesha.

O ni awọn aburo oun mejeeji wa di ọta ara awọn amọ oun mọ pe Ọlọrun yoo ba oun yanju ọrọ naa.