Abiola Ajimobi: Florence ní òun máa lọ ń mu kọfí létí ibojì olóògbé láàràárọ̀

Abiola pẹlu Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi

Ọjọ ti a ba ku laa dere, eeyan o ṣunwọn laaye.

Lẹyin ti o pe ọdun kan ti gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ, Abiola Ajimobi jade laye, iyawo rẹ, Florence, ti sọ pe iku ọkọ ti mu oun dẹkun gbigba adura si Ọlọrun.

Florence fidi ọrọ yii mulẹ ninu ọrọ to sọ lasiko ayẹyẹ eto iranti ọdun kan oloogbe naa, bakan naa lo tun kọ awọn ọrọ awunilori nipa bo se nifẹ ọkọ rẹ si ninu iwe eto ti wọn se fun ayẹyẹ naa.

''Lai ṣe ani ani, ko rọrun fun mi rara lati maa gbe lai si ọkọ lati igba ti olowo ori mi ti jade laye.

Oun ni ololufẹ mi, nitori naa, o nira lati tẹsiwaju fun mi ṣugbọn mo gbagbọ pe ayipada yoo wa lọjọ kan.

Ọrọ imọyi ti Florence Ajimobi kọ fun iranti ọdun kan ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

O ti di aṣa mi lati maa joko si eti iboji rẹ laararọ, ati pe inu mi maa n dun wi pe ọkọ mi nifẹ mi,'' aya Ajimobi ṣalaye.

Ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020 ni gomina ipinlẹ Oyo nigba kan ri dagbere faye, o si wọ kaa ilẹ lọ lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹfa kan naa.

Iyawo Ajimobi ṣalaye pe, oun ati ọkọ oun to ti di oloogbe bayii ko tiẹ sọrọ nipa iku ri ninu irinajo ogoji ọdun ti wọn jọ rin, ki iku to mu un lọ.

''Inu mi dun nigba ti emi ati Biola gbe igbesẹ lọdun 1980 lati ṣe igbeyawo.

Mo le fi gbogbo ẹnu sọ pe emi ati Ajimobi ni ibaṣepọ to dan mọran, ti ẹnikẹni le ni fun ogoji ọdun ti a jọ gbe pọ.

Ṣugbọn iku ko dọjọ, arun ko doṣu, a maa n fi oju ara wa ri ni bi eeyan ṣe n ku, ṣugbọn a ko tii ni iru iriri bayii fun ra, ko to di igba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ.

Ọrọ imọyi ti Florence Ajimobi kọ fun iranti ọdun kan ọkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Mo mọ pe aye mi ti wa sopin nitori iku ti mu ololufẹ to n fun mi lagbara lọ

Ogunjọ oṣu karun un ọdun 2020 ni ayẹwo fihan pe emi ati ọkọ ni arun coronavirus.

Lẹyin naa ni a ya ara wa sọtọ, ti a si bẹrẹ si ni lo oogun wa nile wa to wa ni Ikoyi niluu Eko gẹgẹ bi awọn dokita ti sọ fun wa.

Mo gbadura kikan kikan, mi o tii gbadura bayẹn ri laye.

Awọn ọmọ atawọn ọrẹ mi naa ko gbẹyin ninu adura gbigba, akoko naa jẹ akoko ẹru ati ireti fun mi.

Mo ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo gbọ adura mi, yoo si mu ọkọ mi lara da.

Abiola pẹlu Florence Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Florence Ajimobi

Amọ, lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020, iṣẹlẹ nla ṣẹlẹ, iku wọle mu ololufẹ mi lọ.

Nigba naa ni mo mọ pe aye mi ti wa sopin nitori iku ti mu olololufẹ mi to n fun mi lagbara lọ.

Oju ti mi nitori mo ro pe Ọlọrun ti kọ mi silẹ papaa julọ lẹyin ibaṣepọ ti mo ni pẹlu Ọlọrun.

Mi o ko tiẹ mọ bo ya mo fẹ ya were nigba naa ni, koda o wu mi ki emi naa ku ki n le lọ ba Biola ọkọ mi.

Niṣe ni mo kan n wo awọn pasitọ ti wọn wa gbadura nile wa bi fọto nitori mi ko fẹ gbọ ohun ti wọn n sọ nipa Ọlọrun.

Florence pẹlu Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Florence Ajimobi

Tori pe Ọlọrun yii kan naa ni mo gbadura si lori ilera ọkọ mi eleyii to pada ku.

Ẹkọ ti mo ti kọ ni pe ti a ba padanu ẹbi, inu wa maa n bajẹ gidi gan an, o maa n dabi ẹni pe Ọlọrun ko si pẹlu wa mọ.

Amọ, Ọlọrun ko fi igba kan fi wa silẹ,'' aya Ajimobi lo sọ bẹẹ.

O ni ko si ẹni to le da bi Ajimobi ọkọ oun laelae nitori o yatọ ni gbogbo ọna.