Olusegun Obasanjo: Kò ṣeéṣe kí Buhari kú, kí wọ́n má bùn mí gbọ́

OlusegunObasanjo

Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo ti sọ pe ohun apanilẹrin ni ọrọ ti awọn eeyan n gbe kiri pe ayederu Aarẹ Buhari lo n tukọ Naijiria lẹyin ti ojulowo Muhammadu Buhari ti dagbere faye.

Obasanjo ni ọrọ naa gbilẹ si nitori aṣilo oju opo ikansirraẹni lori ayelujara, eyii to mu ki ọpọ eeyan gba irọ nla naa gbọ.

Aarẹ ana ọhun lo sọ ọrọ naa nibi ipade apero kan, nibi to ti ṣalaye pe eekan ilu kan lo de ba oun lalejo, to si ni ki oun sọ ootọ to wa nidi ahesọ iku Aarẹ Buhari.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni eekan ilu naa ni ọrọ ọhun fa ori ayelujara ya.

Baba Iyabo ni ọrọ yẹyẹ ni pe Buhari yoo dagbere faye, awọn kan yoo si fi ẹlomiran lati ilẹ Sudan rọpo rẹ ti oun ko si ni mọ si.

Àkọlé fídíò, Olowo: Bí ìjọba bá ṣe àtúntò tún yẹ, Sunday Igboho yóò fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú wọn

O ni "Alẹnulọrọ laarin ilu kan lo tọ mi wa, to si n sọ nipa bi Buhari to wa lori oye kii ti ṣe ojulowo Aarẹ Buhari.

Mo wa beere lọwọ ẹni naa boya o gba iroyin ọhun gbọ, oun naa si fesi pe ṣe bi o ti wa lori gbogbo oju opo ikansirasẹni lori ayelujara.

Bawo ni Buhari ṣe maa ku ti a ko ni mọ, ti awọn kan yoo si lọ gbe ẹlomiran wa lati Sudan lati rọpo Buhari?

Balogun Owu tẹsiwaju pe "O jẹ ohun to panilẹrin pe awọn eeyan gba ahesọ ọrọ naa gbọ nitori pe o wa lori ayelujara."

Bo tilẹ jẹ Aarẹ ana ọhun sọ pe anfani nla lo wa ninu lilo awọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara, o ni ohun ibanujẹ ni pe ọpọ eeyan lo n ṣi oju opo naa lo.

Obasanjọ pari ọrọ rẹ pe lilo ẹrọ ayelujara dara pupọ, ṣugbọn awọn ọdọ nilo idanilẹkọ lori awọn ọna ti wọn le gba lo oju opo ọhun, lọna ti yoo ṣe gbogbo mutumuwa lanfaani to jọju.