Baba Ijesha: Iyabo Ojo ní ọ̀pọ̀ àgbà onítíátà ló ń fẹyín sí òun àmọ́ tó ń sọ̀rọ̀ òun lẹ́yìn

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Iyabo Ojo ti sọrọ lẹyin ti ile ẹjọ giga ilu Eko fun Baba Ijesha ni beeli lori ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ ti wọn fi kan.

Iyabo Ojo sọ ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ nipa bi ọrọ se ri laarin rẹ ati agba osere tiata miran, Oloye Aderemi Adedeji ti ọpọ mọ si Baba Olofana.

Bẹẹ ba gbagbe, Olofana lo yọju sile ẹjọ lọjọ Alamisi, to si ba awọn akọroyin sọrọ pe oun pe Iyabo Ojo lori ọrọ Baba Ijesha amọ to yaju si oun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n fesi lori ọrọ yii, Iyabo Ojo ni oun ko fẹ sọ pe agbalagba n pa irọ lori bi Baba Olofana se ni oun yaju si oun.

O ni ohun ti Olofana ba oun sọ ni pe ki oun mase fesi mọ fun Yomi Fabiyi amọ ti oun yari pe kii se oun ni oun yoo dakẹ fun Yomi.

Àkọlé fídíò, Loni Ọjọbọ, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021, ni wọn o tun gbe oṣerekunrin, Olanrewaju Omiyinka, ti ọpọ eeyan mọ si Baba Ijesha, lọ si ile ẹjọ.

"Yomi Fabiyi yoo sọ nnkan miran fun mi lẹyin lori ọrọ Baba Ijesha amọ ti yoo wa soju opo ayelujara lati wa maa sọ nnkan miran, n ko si le fara mọ."

Iyabo fikun pe oun tun sọ fun Olofana pe to ba jẹ ọmọ rẹ ni wọn se asemase si, se yoo ni ki oun dakẹ ni?, ti awọn ko si gbọ ara awọn mọ.

O fikun pe ẹnu ya oun nigba ti Olofana wa n kede pe oun yaju tabi sọ pe "Baba ẹ bọ silẹ nibẹ."

Iyabo ni oun kii pe iru ede bayẹn rara amọ oun ko ni ba baba naa jiyan sugbọn o ni oun tọrọ aforijin to ba jẹ pe ohun ti oun sọ bi Olofana ninu.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, iyaboojofespris

Emi kii se ara ẹgbẹ TAMPAN amọ̀ ọ̀pọ̀ wọ̀n lo n seku sẹyẹ si mi

Bakn naa ni Iyabo Ojo ni oun ko ni ija kankan pẹlu ẹgbẹ awọn oṣere tiata, TAMPAN, lẹyin ti wọn fẹsun kan oun pe o n sọrọ kobajungbe si ẹgbẹ naa.

O ṣalaye pe idi ti oun fi n darukọ TAMPAN lọpọ igba ni pe, awọn agbaagba ẹgbẹ naa n ṣatilẹyin fun oun bi oun ṣe duro digbi lẹyin ọmọ ti wọn ni Baba Ijesha ba lopọ, ṣugbọn nnkan mii ni wọn maa n sọ ti wọn ba de ode ere.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, lara awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ laarin awọn oṣere naa lo n ta oun lolobo lori gbogbo bi wọn ṣe n sọrọ oun lẹyin.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Iyabo sọ pe "Mo ni awọn eeyan ti wọn ti ba mi ṣiṣẹ ri, ti wọn si jẹ eeyan temi nitori mi o ṣe ibajẹ kankan si wọn ri."

"Awọn temi yii lo maa n wa jabọ fun mi nipa ohunkohun ti wọn ba n sọ nipa mi lode ere."

"Ọpọ awọn ti mo bu iyi fun ninu iṣẹ tiata lo maa n fẹyin si mi loju mi ṣugbọn ti wọn maa n sọrọ mi laidaa lẹyin."

Iyabo Ojo sọrọ nipa awọn oṣere to ṣẹṣẹ n goke agba, ti wọn maa n sọrọ odi nipa oun lori ayelujara ti TAMPAN si kọ lati ba irufẹ awọn oṣere bẹẹ wi.

Lẹyin naa lo sọ pe oun ko ni ikunsinu kankan pẹlu TAMPAN gẹgẹ bii ẹgbẹ.

O ni "Mi o ni iṣoro kankan pẹlu TAMPAN, ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ TAMPAN lo jẹ ọrẹ ati alabaṣiṣẹ mi.

Àkọlé fídíò, Jeleosinmi Art Centre: Ibùdó yìí ló ń tọ́ ọ̀dọ́ sọ́nà nípa iṣẹ́ ọnà àti àṣà dípò ìwà àìda

Bo tilẹ jẹ pe mi o si ninu ẹgbẹ TAMPAN ṣugbọn oṣere tiata Yoruba naa ṣi ni mi."

Gbajumọ oṣere naa sọ siwaju si pe TAMPAN nilo lati yanju awọn iṣoro kan to n ba ẹgbẹ ọhun finra labẹnu.

O fi kun pe oun ko ni ikunsinu kankan ẹgbẹ TAMPAN ṣugbọn oun ni ẹtọ lati sọrọ soke lori ohunkohun ti oun ba fẹ.

Iyabo Ojo pari ọrọ rẹ pe, ki TAMPAN darijin oun ti wọn ba ro pe oun ti ṣẹ awọn lọna kan tabi omiran.