Yoruba Nation Kwara: Àwọn ọ̀dọ́ ìlú Ọ̀ffa fàákékọ́rí lórí ìwọ́de 'Yoruba Nation', wọ́n ní Sunday Igboho bú Ọlọ́fà

Iwọde ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti ọpọ mọ si "Yoruba Nation" ti to yẹ ko waye loni nilu Offa foriṣanpọn.
Awọn to n pe fun idasilẹ orilẹede Yoruba labẹ aṣia "Yoruba Nation" ti gunlẹ si ilu Ọffa gẹgẹ bi wọn ti ṣe pinnu rẹ ṣaaju ti wọn si ti bẹrẹ iwọde wọn lati agbegbe Sẹkiteriati ẹgbẹ awọn ọmọ ilu Ọffaa, ODU.
Bi wọn ti n lọ pẹlu oniruuru orin ẹhonu lẹnu wọn ati patako alakọle ti wọn kọ oriṣiriṣi akọle ẹhonu si pẹlu ni awọn agbofinro n wọ tẹle wọn lati rii pe iwọde naa ko jasi rukerudo ni ilu.
Ko pẹ ti iwọde naa bẹrẹ lawọn ọdọ ilu kan ya soju popo lojiji lati da iwọde naa duro eleyi to si fẹ di iṣu ata yan an yan an.
Eyi lo mu ki awọn agbofinro faake kọri pe lọna ati lee dena wahala, iwọde naa ko ni lee tẹsiwaju mọ.
Awọn ọdọ naa fẹsun kan aṣiwaju awọn ẹgbẹ to n pe fun idasilẹ "Yoruba Nation", oloye Sunday Igboho pe o fi ẹnu abuku kan Kabiyesi Ọlọffa ti wọn si ni awọn ko lee la oju awọn silẹ ko maa tabuku Ọbalaye ilu awọn ko si tun fẹ ṣe iwọde ninu ilu bẹẹ.
Oloye Sunday Igboho tabi ẹnikẹni ninu awọn aṣiwaju ẹgbẹ to n pe fun i"Yoruba Nation" ko tii sọ ohunkohun lori iṣẹlẹ yii tabi ẹsun ti wọn fi kan Sunday Igboho.
Ìwọ́de 'Yoruba Nation' ti bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Offa

Iwọde ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti ọpọ mọ si "Yoruba Nation" ti bẹrẹ ni ilu Ọffa.
Lasiko ti a fi nko iroyin yii jọ awọn to n lewaju ipe fun idaduro ilẹ Yoruba atawọn ọdọ ni ilu Offa ti n ko ara wọn jọ si agbegbe Sẹkiteriati to wa nilu Ọffa nibi ti wọn ti gbera fun iwọde wọn.
Bakan naa lasiko ti a fi nko iroyin naa jọ Oloye Sunday Igboho ko tii darapọ mọ iwọde naa.
Òní ni ìwọ́de Yoruba Nation yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara
Oni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2021 ni iwọde Yoruba Nation yoo waye ni ipinlẹ Kwara.
Iwọde na ti ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua n ṣe onigbọwọ rẹ ni ireti wa pe yoo waye niluu Offa, ti yoo si bẹrẹ ni aago mẹwaa aarọ lonii ọjọ Abamẹta.
Gẹgẹ bii ohun ti awọn to n ṣagbatẹru iwọde naa sọ, wọn ni awọn ko fẹ ogun tabi itajẹsilẹ, ṣugbọn afojusun awọn ni ki ilẹ Yoruba yapa kuro lara orilẹ-ede Naijiria, ko si da wa laaye ara rẹ gẹgẹ bii orilẹ-ede to ni ominira.
- Iná sọ níléẹ̀kọ́ ìjà "Kongfu! Àwọn ọmọdé tó ń kọ́ ìjà ààbò ara ẹni jó ráúráú
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
- Gọngọ́ sọ, àwọn Ṣọ́jà lé ọlọ́pàá lùgbẹ́ lágọ́ ọlọ́pàá l' Osogbo
- Ẹ gbà wa o! Ìwé ìrìnà àti ìwé ìgbélùú wa ní Oman ti "expire", wọ́n tún ní Nàìjíríà ti di ibi àìwọ̀
- Kà nípa ìṣẹ́dá àwọn tí kíní abẹ́ wọn ò dúró tẹ́yin olóyìnbò ń pè ní "Paedophile" àmọ́ n'ílànà ìṣẹ̀ṣe
- Ọ̀rọ̀ wo ni Sheikh Gumi sọ tí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ní kó wá ṣàlàyé ara rẹ̀?
- Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn Ajimobi, èrò wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀!
- Wo iléẹ̀kọ́ tí wọ́n kò ti fààyè gba akẹ́kọ̀ọ́ láti padà sọ́dọ̀ Òbí tàbí ìlú rẹ̀ lẹ́yìn tó bá parí
- Ọmọ ọdún méje ni mo ti ń digunjalè, ogun ìdílé ló fàá, afurasí ṣàlàyé l'Ondo
- Ẹ wo bí ọ̀nà àbáyọ tí adigunjalè bá kọ lẹ́tà sí yín pé àwọn fẹ́ ẹ́ wá jà yín lólè
Ṣaaju ni iwọde naa ti kọkọ waye lawọn ilu nla nla bii Osogbo, Ibadan, Akure, Ado Ekiti, ti ireti ṣi wa pe yoo de ilu Eko laipẹ yii.
Lara awọn alẹnulọrọ lawujọ ti awọn eeyan n reti nibi iwọde ọhun ni ajijagbara Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho.
Lasiko ti agbẹnusọ Igboho, Koiki Media, n kede iwọde ọhun loju opo facebook rẹ, o ni ko si ohun ti yoo yẹ iwọde naa.
O si tun kede fun gbogbo awọn ti yoo yọju sibi iwọde ọhun lati lo ibomu lọna ati bọwọ fun ilana ajakalẹ arun Covid-19 nitori obitibiti ero ti wọn n reti nibẹ.
Ẹwẹ, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo n ṣatilẹyin fun Yoruba Nation yii, ọpọ awọn mii n sọ pe iyapa kọ ni ọna abayọ si iṣoro ti Naijiria n doju kọ.
Bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn ori ade nilẹ Yoruba lo ti ṣo ni gbangba pe digbi lawọn wa lẹyin Yoruba Nation, ṣugbọn awọn ori ade mii bii Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ni ohun kan ṣoṣo to le gbe Naijiria de ilẹ ileri ni ki gbogbo ẹya to wa ni Naijiria ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ.














