Nigerian Cryptocurrency: Báwo ni ilé ẹ̀kọ́ Kano yìí ṣe ń gbà Crypto lọ́wọ́ òbí akẹ́kọ̀ọ́

Aworan afihan Crypto currency

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Airinjina lai ri abuke ọkẹrẹ!

Ileẹkọ aladani kan ni Kano ti sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni gba ki akẹkọọ maa fi Crypto san owo.

Ọga ile ẹkọ naa Sabi'u Musa sọ fun BBC pe awọn gbe igbesẹ nitọri bi ọpọ eeyan ṣe n tẹwọgba owo oju opo ayelujara yii.

Arakunrin Sabi'u fi igbesẹ tuntun yii to awọn akọroyin leti to si ni ileẹkọ New Oxford Science Academy to wa ni Chiranchi finufẹdọ fẹ ṣe bẹẹ ni.

O ni awọn ko gbe igbesẹ yii lai ṣe pe awọn fi to awọn obi akẹkọọ awọn leti.

"Ohun to mu wa gbe igbesẹ yii ko ṣẹyin bi ọpọ eeyan ṣe n lo irufẹ owo yii lori ayelujara''.

"A si dupẹ pe ti ẹ ba wo o daada, ẹ o ri pe awọn orileede bi El-Slavador ti faaye gba lilo cryptocurrency gẹgẹ bi owo fun idunadura''

Àkọlé fídíò, Alhaja Rukayat Batimoluwasi Oniwaka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀

O tẹsiwaju pe ''Bi a ba wo nkan tawọn onimọ nipa ọrọ aje n sọ, o ṣeese ki Cryptocurrency ti fẹsẹ rinlẹ ni nkan bi ọdun meloo si igba taa wa yii''

Sabi'u sọ pe idi ree ti o fi yẹ ki Naijiria tete maa gbaradi ki wọn baa ma wa kabamọ.

O ni ''lootọ a o tii gun oke agba laarin awọn orileede to ku ṣugbọn o yẹ ka ṣamulo ilana yii ka baa le ni idagbasoke to yẹ''.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Ko ṣe dandan lati fi Crypto san owo ilewe f'ẹni ti ko ba fẹ

T'ohun ti gbogbo alaye ti Sabi'u ṣe, o ni ko ṣe dandan lati fi Crypto sanwo bi kii ṣe pe o ba wu awọn obi.

''Pupọ awọn obi lo ti sowọpọ pẹlu wa lori igbesẹ yii koda awọn kan wa fi owo Dutch Coin sanwo nibi lana alana yii''.

O tẹsiwaju pe ọkan ninu awọn obi sọ pe inu oun dun si ilana owo sisan yii.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lori bi wọn ti ṣe n gba san owo naa, Sabi'u ṣalaye pe niṣe lawọn n pese oju opo akoto owo ileẹkọ naa tawọn obi a si maa san bitcoin wọn sibẹ.

Kii ṣe ka kan maa na owo loju ayelujara la fi n ṣe bi kii ṣe pe ki a maa lo oju opo yi fun idunadura wa.

Ọga ileẹkọ naa fi idunnu rẹ han lori igbesẹ yi to si ni oun nigbagbọ pe laipẹ yi yoo tun gbooro sii.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Amọ ṣa ajọ to n mojuto eto pasiparọ owo ni Naijiria Securities and Exchange Commission of Nigeria (SEC) sọ pe awọn ko tii ṣetan lati buwọlu lilo owo yii ni idunadura.

Eyi wa ni ibamu pẹlu ọrọ banki apapọ CBN to ni awọn ko ti ṣetan lati faaye gba lilo owo yii ayafi ti gbogbo eto ba wa ni ṣẹpẹ.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di