Nigerian cryptocurrency: Àwọn orílè-èdè bí China, India, Iran náà ti fi òfin de owó Crypto

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Ẹti ni banki apapọ Naijiria pasẹ pe banki kankan ko gbọdọ ṣe katakara owo ori ayelujara, Crypto (Dogecoin, Bitcoin, ati Ethereum) mọ. Ọpọlọpọ awuyewuye lo si ti n waye lori àṣẹ naa jakejado Naijiria. Awọn ileesẹ iroyin kan ni Naijiria sọ pe nitori ikilọ ti ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ America, FBI, fun banki apapọ Naijiria ni wọn fi fofin de Crypto.

Ko sẹyin bi onijibiti to n lo owó Crypto lati ko ọpọlọpọ miliọnu Dọla ilẹ America ti wọn ko jọ lọna aitọ lati àwọn orilẹ-ede kan ati America, wò Naijiria, ni banki apapọ naa se pàṣẹ. Sugbọn ṣa, kii ṣe orilẹ-ede Naijiria nikan lo ti fi ofin de owo Crypto.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Ọmọ Yahoo tú àṣírí ara rẹ̀ fún, bí wọ́n ṣe ń ṣe é BBC Yorùbá

China

Ninu oṣu Kẹsàn-án, ọdun 2017 ni China bẹrẹ igbesẹ lati fi ofin de pasipaarọ Bitcoin lorilẹ-ede naa. Awọn ilu bi Beijing ati Shanghai lo si ti bẹrẹ.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ofin naa jẹ ara igbesẹ ijọba China lati mu adinku ba ewu to wa fun eto owó nina lorilẹ-ede naa. Banki apapọ China fi ikilọ sita lori itakun agbaye kan to gbe kalẹ pe awọn eeyan kan n lo owo Crypto lati hu iwa ọdaran bi katakara oogun oloro, fayawọ, kiko owo pamọ lọna aitọ, ati ikowojọ ti ko ba ofin mu.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ni àwọn onijibiti le ma a lo lati gbọ bukaata igbesunmọmi, kiko owo pamọ lọna ti ko ba ofin mu, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Koda lọdun 2019, awọn alasẹ ni Iran gbẹsẹ le ẹgbẹrun kan irin'ṣẹ iwakusa Bitcoin, to jẹ ti ileesẹ meji to ti ko igba wọle, nitori pe ina ijọba ti wọn n lo ti pọ ju

India

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2018, banki apapọ India kede pe ofin ti de rira tabi tita owo Crypto. Koda, oṣu mẹta ni Reserve Bank of India, fun awọn banki naa lati fi opin si okoowo naa.Eeyan bi miliọnu marun-un lo n lo owo Crypto ni India lasiko naa.

Bangladesh

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2017 ni banki apapọ Bangladesh fi ofin de lilo owo Bitcoin. Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti sọ pe nina owo naa le fa titapa si ofin to de gbigbọ bukaata igbesunmọmi ati kiko owo pamọ lọna ti ko ba ofin mu.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Morocco

Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2017 ni iroyin jade pe banki apapọ ati ileesẹ to n ri si pasipaarọ owo ilẹ okeere ni Morocco ti fofin de nina owó Crypto. Ati pe ijiya nla ni fun ẹnikẹni to ba gba owó lati ilẹ okeere tabi san owó silẹ okeere lai lo àwọn ajọ ti ijọba fi àṣẹ fun, tabi gba owo ilẹ okeere ti ko si ninu akọsilẹ Bank Al-Maghrib.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Wọn ni ewu nla ni fun awọn to n na owo naa, nitori pe owo naa ṣe e lo lati ṣe katakara oogun oloro, nkan ijagun ati owo itusilẹ fun ẹni ti wọn ba ji gbe.

Uganda

Ọdun 2019 ni banki apapọ ati ileesẹ ijọba Uganda to n mojuto ọrọ owo nina kilọ fun awọn eeyan pe ki wọn o ma a na owo Crypto nitori pe ijọba ko tẹ́wọ́ gba a. Ijọba sọ pe ọpọlọpọ owó Crypto ni ko ni atilẹyin ijọba tabi eto adojutofo.

Aworan afihan Crypto

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni ileesẹ naa sọ pe ko si aabo fun awọn to n na owo naa ni Uganda, ti ohunkohun ba sẹlẹ si owo wọn.

Zambia

Bakan naa ni banki apapọ Zambia, kilọ fun awọn eniyan orilẹ-ede naa ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2018 lori nina owó Crypto, to si ran wọn létí pe kii ṣe owó to ṣe itẹwọgba lorilẹ-ede naa. Lara ewu ìwà ọdaran ti banki naa sọ pe o rọ mọ nina owó naa ni kiko owó pamọ lọna ti ko tọ ọ, jibiti, ati gbigbọ bukaata awọn agbesunmọmi. Pẹlu àṣẹ ti banki apapọ Naijiria pa yii, ọpọlọpọ miliọnu Dọla owó Crypto ni yoo ha si Naijiria, to jẹ orilẹ-ede kejì ti okoowo Bitcoin pọ si julọ l'agbaye. Bitcoin to le ni ẹgbẹrun lọna ọgọta ni awọn ọmọ Naijiria ti fi dokoowo lati ọdun 2015.