Mariam kàgbákò ikú lọ́wọ́ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ òní Yahoo-yahoo tó dáná sún un lórí ẹsùn àgbèrè

Oríṣun àwòrán, Google
Arabinrin kan ti ọrékunrin rẹ dana sun nilu Eko lori ẹsun agbere ti gba ibẹ lọ si ọrun alakeji.
Arabinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Mariam Alabi ti a si gbọ pe o jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogun jẹ Ọlọrun nipe lẹyin ti gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ ja si pabo ni ile iwosan ijọba apapọ to wa ni Igando nilu Eko.
Arakunrin Victor Orji to jẹ ọrẹkunrin rẹ ni ile iṣẹ ọlọpaa nilu Eko sọ pe o dana sun Mariam.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ọlọpaa nilu Eko Bala Elkana ti ṣaaju fi sita pe iṣẹlẹ bi Victor ti ṣe dana sun Mariam waye ni ọjọ Abamẹta ladugbo Ọjọọ nibi tawọn mejeeji ti jọ n gbe ile pọ.
''Loju opo ayelujara ti awọn eeyan ti n yan ọrẹ ni Ifeanyichukwu ti pade arabinrin naa ni oṣu Keji ọdun yii ti o si ko lọ ba a nile rẹ ni oṣu Kẹta ọdun.
O ti n ṣe iṣẹ Yahoo yahoo lati nnkan bii ọdun mẹta ti o si n fi owo to ba ri nibẹ san owo ile to gba, ki o tun fi gbadun aye rẹ''.
Elkana fi kun un pe ọrọ ko wọ laarin awọn mejeeji nigba ti Mariam yọlẹ kuro nile lọjọ Ẹti lati lọ pade ọkunrin miran.
''Ni igba ti asiri tu si Ifeanyichukwu lọwọ, lo ba fi ibinu da bẹntiroo si Mariam lara ti o si dana sun un''
Elkana sọ pe awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuye yọju sibi iṣẹlẹ naa ti wọn si gbe Mariam lọ si ile iwosan ijọba.
O ni, o ṣeni laanu pe ile iwosan naa lo dakẹ si lowurọ ọjọ Aiku.
Elkana pari ọrọ rẹ pe ọga ọlọpaa nilu Eko, Hakeem Odumosu ti ni ki wọn fi afurasi naa si ahamọ titi ti yoo fi foju ba ile jọ bi ofin ṣe laa kalẹ.














