Ìkànìyàn: A ti tó igba mílíọ́nù èèyàn ní Nàìjíríá

Ojú ọ̀nà tí kò dára

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ni iye ènìyàn ti pọ̀ gan láì sí ìgbéga tó báa àwọn ohun amáyérọrùn.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, òǹkà iye ènìyàn tó wà lórílẹ́èdè Nàìjíríá ti sún mọ́ mílíọ̀nù lọ́nà igba.

Èyí ni àtẹ̀jáde tó wá láti ọ̀dọ̀ àjọ tó ńrísí ìkànìyàn lórílẹ́èdè Nàìjíríá eléyìí tó fi orílẹ̀èdè yìí sí ipò keje nínú àwọn orílẹ̀èdè tó pọ̀ jù lágbayé.

Gẹ́gẹ́ bí akọ̀ròyìn ilé isẹ́ BBC tó wà nílu Abuja, Chris Ewokor se sọọ́, adarí àjọ tó ńrísí ìkànìyàn lórílẹ́èdè Nàìjíríá sọ wípé, péréte mílíọ̀nù mẹ́jì ló kù kó ká ígba mílíọ̀nù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò, Olú Fálaè: Orúkọ àwọn jẹgúdújẹrá tí APC tẹ̀ jáde kò tíì pé

Wọ́n se àgbéjáde òǹkà yìí ní New York lọ́jọ́ ajé níbi ìjókòó ìkọkànléláàdọ́ta ti àjọ náà lórí iye ènìyàn àti ìdàgbàsókè.

Alága àjọ náà, ọ̀gbẹ́ni Eze Duruiheoma ní, wọ́n ńní àfojúsùn wípé ó yẹ kí orílẹ̀èdè Nàìjíríá di ipò kẹta nínú àwọn orílẹ̀èdè tó pọ̀ jù lágbayé ní ọgbọ̀n ọdún sí ìsinsìyìí.

Èrò wìtìwìtì lórílẹ́èdè Nàìjíríá

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ó ti di igba mílíọ̀nù ènìyàn ó dín díẹ̀ tó wà lórílẹ́èdè Nàìjíríá

Ó Jẹ́ kó di mímọ̀ pé láti àádọ́ta ọdún sẹ́yìn ni iye ènìyàn tó wà ní àwọn ìlú ńlá ti pọ̀ gan láì sí ìgbéga tó báa mu ní ti àwọn ohun amáyérọrùn.

Àìrísẹ́se àwọn ọ̀dọ́ leè fa wàhálà lẹ́sẹ̀

Lọ́sẹ̀ tó kọjá, asojú ilẹ̀ Britain sí orílẹ̀èdè Nàìjíríá, Paul Arlwright fi irú ìjẹlọ́kàn yìí kan náà hàn níbi ìpàdé àpérò kan nílu Abuja.

Ó ní bí wọn ò bá sọ́ra, ìkọlùkọgbà ńrúgbó bọ̀ pàápàá pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀dọ́ tí kò nísẹ́ lọ́wọ́ tí ètò ẹ̀kọ́, ìlera, àti àmúlò ohun àlùmọ́nì kò sì sí lárọ́wọ́tó wọn.