Ìpànìyàn Ìjẹ̀bú Igbó: Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ afurasí 29

Àwọn ọlọ́pàá tó ń pèsè ààbò lójú pópó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọlọ́pàá kìí jáfara láti dá àlàáfíà padà sáwọn ágbègbè tí wàhálà bá ti ń wáyé

Iléesẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ògùn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọwọ́ òun ti tẹ afurasí mọ́kàndínlọ́gbọ̀n lórí ìpànìyàn tó wáyé ní Ìjẹ̀bú Igbó ní aago márùń ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ọ́jọ́ àìkú ní agbègbè Òkè-Sopen, tó sì sún wọ ìdàjí ọjọ́ ajé, èyí tó tún tàn wọ àwọn àdúgbò míì bíi Òkè Àgbò àti Ojowo.

A gbọ́ pé kò dín ní ẹ̀mí mẹ́ta, nínú èyí tí a ti rí aráàlú méjì àti Ìsìpẹ́kítọ̀ ọlọ́pàá kan, tó bá ìpórógan tó wáyé láàrin ẹgbẹ́ OPC àti ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ní ìlú Ìjẹ̀bú Igbó ọ̀hún lọ.

Gẹ́gẹ́ bíí Alukoro fún iléesẹ́ Ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ògùn, Abimbọla Oyeyẹmi ti wí, ìsẹ̀lẹ̀ náà kò ní ohunkohun se pẹ̀lù ọ̀rọ̀ òsèlú, pẹ̀lú àfikun pé àwọn ọlọ́pàá tún gba ìbọn lọ́wọ́ àwọn afurasi naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹ gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Abimbọla Oyeyẹmi sọ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà"

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Ìpànìyàn Ìjẹ̀bú Igbó: Ọwọ́ Ọlọ́pàá tẹ afurasí 29

Nígbà tí òun náà ń sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ yìí, Alukoro fún ẹgbẹ́ ọmọ bíbí Oòduà, OPC, Ọ̀gbẹ́ni Sina Akinpẹlu ní "isẹ̀lẹ̀ náà bani nínújẹ́ púpọ̀ sùgbọ́n OPC kọ̀ ní gbé ìgbẹ́sẹ̀ láti fẹ sẹ̀lẹ̀ náà lójú.

Ó wá rọ iléesẹ́ Ọlọ́pàá láti ri dájú pé àlàáfíà tètè padà jọba lágbègbè náà nítorí ilẹ̀ Yorùbá kò gbọdọ̀ bàjẹ́.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Wàhálà Ìjẹ̀bú Igbó: OPC sọ ohun tó bí ìsẹ̀lẹ̀ náà