Corruption: Ìwádìí àjọ aṣèṣirò òde, NBS gbé e jáde pé àwọn ọlọ́pàá, adájọ́ àtàwọn aṣọ́bodè ló gba rìbá jùlọ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Njẹ o mọ pe ileeṣẹ ọlọpaa, awọn oṣiṣẹ ẹka ipẹjọ fun ijọba, awọn adajọ atawọn oṣiṣẹ aṣọbode lo gba riba julọ lorilẹ-ede Naijiria?
Ma ṣe haa o, ohun ti iwadii ajọ aṣesiro ode lorilẹ-ede Naijiria, Nigeria Bureau of Statisics, NBS lo fi idi rẹ mulẹ ninu iwadii to ṣe to si gbe abajade rẹ sita fun aye ri lọjọ Ẹti.
Iwadii naa ni o ṣeni laanu pe awọn oṣiṣẹ agbefọba ti pataki iṣẹ ilu nbẹ ni ikawọ wọn atawọn to wa ni iṣkoso ofin gan ni a n ba nidi iwa ibajẹ naa.
Bakan naa ni iwad\ii ọhun tun fidi rẹ mulẹ pe, ninu gbogbo awọn owo riba ti awọn ọlọpaa, olupẹjọ ijọba, adajọ atawọn ileeṣẹ ologun gba, ida mẹta ninu rẹ lo jẹ wi pe awọn gan an funrawọn lo beere fun un.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O fi kun un pe, ida mọkanlelogun awọn obinrin to n gbe ni igberiko lo san owo ẹyin fun oṣiṣẹ ijọba kan ninu gbogbo awọn obinrin igberiko to ni ohun kan tabi omiran lati ṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ijọba laarin oṣu mejila to ṣaaju iwadii ọdun 2019 yii.
Ẹwẹ iwadii naa tun fi kun un pe riba gbigba ti sọ eto igbanisiṣẹ lorilẹ-ede Naijiria di toni owo ree, iṣẹ ree.

Oríṣun àwòrán, @CustomsNG
Abajade iwadii ajọ aṣeṣiro ode naa jẹ ko di mimọ pe omilẹgbẹ awọn to riṣẹ lo ni awọn san owo ki awọn to ri iṣẹ.
Ida mejilelọgbọn awọn to ri iṣẹ ijọba laarin ọdun mẹta sẹyin ni wọn sanwo riba ki wọn to ri iṣẹ ijọba gba eleyii to pọ ju irufẹ ayẹwo bẹẹ ni ọdun 2016 ni ilọpo meji.
Ni ti ẹlẹkunjẹkun, ẹkun aaringbungbun guusu Naijiria (South-south 35.4%) ni iwa riba gbigba ti gogo julọ.
Lẹyin naa ni ẹkun aaringbungbun ariwa orilẹ-ede Naijiria, (North central 32.6%)
Amọṣa ni ti ipinlẹ si ipinlẹ, ipinlẹ Kogi ni iwa riba gbigba ti pọju lọ lorilẹ-ede Naijiria, lẹyin naa ni ipinlẹ Gombe tẹlee.














