Ikoyi Prisons: Iléeṣẹ́ Ọgbà ẹ̀wọ̀n ní kí wọ́dà mẹ́jọ lọ rọ́ọ́kún nílé lórí ikú ẹlẹ́wọ́n márùn ún l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ Ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria ni awọn ti ran awọn wọda mẹjọ lọ rọọkun nile Lori iku ẹlẹwọn marun ti waya ina ja lu lọjọ aje
Ni owurọ ọjọ aje, ọjọ keji oṣu kejila ọdun 2019 ni iroyin iku awọn ẹlẹwọn marun to ku iku ojiji lu si igboro. Ohun ti awọn alaṣẹ Ọgba ẹwọ sọ ni pe waya ina kan lo ja nitori apọju agbara ina ti awọn ileeṣẹ manamana mu de. Rẹgi ori ibusun ti awọn ẹlẹwọn naa wa ni o ja le ti o si pa awọn marun lẹsẹkẹsẹ, ti awọn meje miran si di ero ileewosan.
Lọjọ naa, ni kete ti minisita fun ọrs abẹle, Rauf Arẹgbẹṣọla bẹ ọgba ẹwọn Ikoyi ni ilu Eko, nibi ti ọrs naa ti ṣẹlẹ wo tan lo ti ṣeleri pe iwadii yoo waye lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan.
Agbẹnusọ kan fun ileeṣẹ ọgba ẹwọn ṣalaye pe wọn gbe igbesẹ naa lati lee raye ṣe iwadii naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ lai si idiwọ tabi idena kankan.








