Aisha Buhari-Aya ààrẹ, Aisha Buhari ni ààrẹ gan kó mọ nípa ọ̀rọ̀ ìyàwò tuntun

Aisha Buhari, aya aarẹ

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari/ twitter

Aya aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ti sọ wi pedigbi bayii ni ọkan oun duro nigba ti ariwo aarẹ fẹ gbe iyawo tuntun bọ si igboro aye lorilẹede Naijiria.

Aisha Buhari ṣalaye ọrọ yii ninu ọrọ kan to sọ lori ileeṣẹ Mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria.

Aya aarẹ orilẹede Naijiria ṣalaye wi pe, aarẹ Buhari gan ti iroyin n sọ pe o fẹ gbe iyawo tuntun ko mọ ohun to n lọ.

O ni awọn kan ni ileeṣẹ aarẹ lo wa nidi iroyin ọhun lori ayelujara.

Laipẹ yii ni iroyin gbode lori ikanni ayelujara ati iroyin gbogbo pe aarẹ Muhammadu Buhari fẹ gbe ọkan lara awọn minisita rẹ, Sadiya Farouq niyawo.

Bi o tilẹ jẹ wi pe ko si ẹni to ms ibi ti iroyin naa ti ṣẹ wa nitori pe lẹyin o rẹyin igbeyawo naa ko waye, Aisha ni ko si eyikeyi ninu oun ati ọkọ oun to mọ ohunkohun nipa iroyin naa.

Arabinrin Aisha Buhari ni gbogbo eeyan lo mọ pe Naijiria ko ni abo labẹ iṣejọba ọkọ ohun, ṣugbọn o da oun loju pe asiko to lati mu nnkan bọ sipo fun awọn ọmọ orilẹede Naijiria.

O ni ọpọ akoba ni oṣelu oni baba isalẹ n ṣe fun iṣejọba lorilẹede Naijiria, idi ti gbogbo awọn minisita ti ọkọ oun, iyẹn Aarẹ Buhari yan gbọdọ fi ji giri dide si iṣẹ to yẹ.