Rotimi Amaechi: Rotimi Amaechi, mínísítà fétò ìrìnnà ní àwọn ọmọ Nàìjíríà tí kò lóye ló já ọrẹ́ ìyà fún òun nílùú Madrid

Rotimi Amaechi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Amaechi/twitter

Rotimi Ameachi to jẹ minisita fun eto irinna lọwọlọwọ bayii ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari ti pariwo sita pe lọsan ọjọ Ẹti, awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan ni ilu Madrid, Orilẹede Spain ja pankẹrẹ iya fun oun.

Bi o tilẹ jẹ pe iṣẹ ilu ni Amaechi ba lọ si orilẹede Spain, Rotimi Amachi ni ọpọlọpẹ awọn ọlọpaa lo gba ohun silẹ lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria naa bi bẹẹ kọ, boya ẹkọ o ba ṣoju mimu fun oun.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ

Minisita fun eto irinna ilẹẹwa naa ni oun dupẹ lọwọ ori pe iwọn ni ikọlu naa mọ, oun ko si farapa, bẹẹ lo fi kun un pe awọn ọmọ orilẹede yii ti ọrs ko ye daadaa lo kọlu oun.

Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ninu ọdun 2019 yii naa ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria kan din dundu iya fun igbakeji aarẹ ile aṣofin orilẹede Naijiria tẹlẹ, Sẹnetọ Ike Ekweremadu lorilẹede Germany.