Robbery notification: Ẹ wo ọ̀nà àbáyọ tí adigunjalè bá kọ lẹ́tà sí yín pé àwọn fẹ́ ẹ́ wá jà yín lólè

Ibọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Onimọ kan nipa eto aabo, Ọgbẹni Akin Adeyi ti sọrọ lori nkan ti awọn araalu le ṣe nigbakuugba ti wọn ba gba lẹta ẹru lọwọ adigunjale.

Nigba ti BBC ba sọrọ lori iroyin to n lọ nipa awọn adigunjale kan to kọ lẹta si adugbo Olopa Estate, Ofatede, nijọba ibilẹ Egbedore, nipinlẹ Osun, Ọgbẹni Adeyi sọ pe nkan akọkọ fun iru adugbo bẹẹ lati sẹ ni pe ki wọn o bẹrẹ si ni fi oju silẹ lati ri awọn nkan to yẹ.

"O yẹ ki awọn ara adugbo naa yẹ ara wọn wo, lati mọ awọn eeyan buruku to n gbabọde laarin wọn."

O ni o sẹ pataki fun awọn to ba n gbe niru adugbo bẹẹ, lati ma ṣe akiyesi irinsi gbogbo eeyan ni adugbo wọn, paapaa awọn to ba jẹ ajeeji tabi ti iṣesi wọn mu ifura dani.

Bakan naa lo sọ pe ki awọn ara adugbo fi nkan ifura ti wọn ba ri to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni kiakia, nitori pe imọ ti awọn ọlọpaa ba ni, ni wọn o fi pese abo.

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè

Akin Adeyi ni: "Gbigbe igbesẹ oju ni alakan fi n sọri ni ọna abayọ to le dena iru awọn nkan bayii."

O ṣalaye pe gẹgẹ bi olugbe nilu Osogbo, oun le fidirẹ mulẹ pe kii ṣe igba akọkọ niyii ti adigunjale kọ lẹta si adugbo naa.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

O ni ṣugbọn iyatọ to wa ninu lẹta ti wọn kọ lọtẹ yii ni bi wọn ṣe ni ki wọn o ko owo itanran fun alaga ẹgbẹ awọn larinlọọdu ni adugbo naa.

O tẹsiwaju pe iwadii yẹ ko waye lori aṣẹ naa, botilẹ jẹ pe ẹnikẹni ko ti i le sọ boya alaga naa mọ tabi lọwọ si iṣẹ awọn adigunjale naa.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Àwọn adigunjalè kọ lẹ́tà sí adúgbò, wọ́n ni kí ara àdúgbò dá 20m tàbí kí wọ́n ó jàwọ́n lólè

Ibẹru -bojo lo gbalẹ laarin awọn olugbe agbegbe Olopa Estate, Ofatede, nijọba ibilẹ Egbedore, nipinlẹ Osun, lẹyin ti awọn adigunjale kọwe ranṣẹ si wọn pe awọn yoo ja wọn lole.

Ibọn ti wọn na soke

Oríṣun àwòrán, @WeArePindula

Lẹta naa, ti wọn kọ ni ede oyinbo ati Yoruba, ni wọn ti paṣẹ fun awsn to n gbe ni agbegbe naa pe ki wọn o da ogun miliọnu Naira jọ , lati dena ki awọn ma ba a ja wọn lole.

Yatọ si eyi, awọn adigunjale naa sọ pe ọwọ alaga ẹgbẹ awọn olugbe ni adugbo naa ni ki wọn o tọju owo naa si, ko le rọrun lati gba nigba ti awọn ba de.

Wọn ni "eyi ni lati sọ fun yin pe , awa ole n bọ wa a ja gbogbo ile to wa ni adugbo yin lole, tabi ki ẹ da ogun miliọnu Naira jọ , ki ẹ si tọju rẹ si ọdọ alaga yin, ka le gba a nibẹ ti a ba de.

"Pẹlu agbara ni a n bọ, ao si pa eyikeyi oṣiṣẹ alaabo yin to ba gbiyanju lati di wa lọwọ."

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Ẹnikan to n gbe ni adugbo naa to ba awọn akọroyin sọrọ sọ pe lati igba ti wọn ti kọ lẹta naa ni awọn eeyan kan ko ti sun ile wọn mọ, to si jẹ pe ọsan ni wọn ma n wa si ile lati ko awọn nkan ti wọn ba nilo.

Ati pe awọn ọlọdẹ to jẹ oṣiṣẹ alaabo ti pọ si ni adugbo naa.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di