Abiola Ajimobi one year memorial: Yemi Osinbajo, Aregbesola, Ganduje péjú síbi ìrántí ọdún kan Ajimobi, wọ́n ní àwọn ń sàárò ọgbọ́n ìṣèjọba àti òṣèlú rẹ̀

Florence ajimọbi pẹlu awọn oloogbe Abiọla Ajibi

Oríṣun àwòrán, Abiola ajimobi foundation

Oloṣelu to ni imọ to kuna nipa ipẹtusaawọ ni oloogbe Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi, o si lo ims naa ni ẹkunrẹrẹ lati fi mu ayipada rere ba ipinlẹ Ọyọ.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo lo sọ eyi nibi aṣeyẹ iranti ọdun kan ti gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi jade laye.

Ayẹyẹ naa waye ni gbọngan nla International Conference Centre, ICC ni fasiti Ibadan.

Awọn eekan lawujọ bii Gomina ganduje ti ipinlẹ Kano, Gomina Abiọdun ti ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla to jẹ minisita fọrọ abẹle,

Awon mii ni: gomina tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ Oloye Adebayọ Alao Akala , minisita fọrọ ọdọ ati ere idaraya, Sunday Dare,

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè

Yetọ si minisita fun ibara ẹnisọrọ tẹlẹ, Amofin Adebayọ Shittu, igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Ayedatiwalo wa nibẹ.

Bakan naa ni aya igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, arabinrin Dọlapọ Osinbajo atawọn aya gomina ipinlẹ Ọṣun, Edo, Ekiti, Ogun, ati Delta ni wọn peju sibi ayẹyẹ iranti Sẹnetọ Ajimọbi naa.

Gomina Ganduje ati Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla

Oríṣun àwòrán, Insightlinks.net

Igbakeji aarẹ Osinbajo, ẹni ti gomina ipinlẹ Ogun, Gomina Abiọdun ṣoju fun fi kun pe awọn n saaro ọgbọn iṣejọba ati oṣelu to ni.

Ninu ọrọ tirẹ igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan ṣalaye pe Sẹnetọ Ajimọbi ti ṣe iwọn to lee ṣe fun ipinlẹ Ọyọ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Ẹwẹ, gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ọyọ , Ọtunba Adebayọ Alao Akala ṣalaye pe oloṣelu ti eeyan n kan saara si ni Ajimọbi nitori ootọ inu to ni ati aimọ bi a ṣe n fi ọrọ si abẹ ahọn sọ ti yoo si sọ ti inu rẹ laifi ti ẹya tabi ẹsin ṣe.

Ajimobi

Oríṣun àwòrán, @Ajimobi

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn Ajimobi, èrò wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀!

Oni ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹfa lo pe ọdun kan lẹyin ti mọlẹbi Senatọ Abiola Ajimobi kede iku rẹ.

Ajimọbi lo ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Oyo fun saa ọdun mẹrin lẹẹmeji ni eyi to fi fopin si ọrọ pe Ibadan kii sin eeyan lẹẹmeji.

O jẹ ọkọ Florence, o bi ọmọ lọkunrin ati lobinrin o si tun jẹ senatọ nigba kan ri ki ọlọjọ to de.

Ajimobi

Bi àwọn kan ṣe n yin in pe alaafia joba nipinlẹ Oyo lasiko Ajimobi ti ohun gbogbo rọwọ rọsẹ.

Naa ni wọn ni awọn eeyan n fẹdọ lori oronro sun lasiko rẹ ni.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....
Ajimobi

Eyi wu mi ko kuku wu ọ lọrọ ile aye.

Ohun naa lo n jẹ ki awọn miran maa bu Abiola Ajimobi lẹyin iku rẹ pe ko si ohun tuntun labẹ ọrun lori awọn iṣẹ to ṣe ki ọlọjọ to de nipinlẹ Oyo.

Ajimoba
Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Ajimobi ṣì ń dá wa lọ́rùn, kódà lẹ́yìn ikú! Ìdí rèé tí ẹ ò lè yínmú sí - Oyo APC

Ajimobi ṣì ń dá wa lọ́rùn, kódà lẹ́yìn ikú - Oyo APC

Bi pọpọṣinṣi ayẹyẹ iranti iku oloogbe Abiola Ajimobi to jẹ gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ṣe n waye kaakiri ni ipinle Oyo

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti tun wu ọrọ jade wipe iranti nipa ipa rere ti eekan adari oṣelu yii fi lelẹ ko ni parẹ lọkan awọn araalu.

abiola ajimobi

Oríṣun àwòrán, Instagram/abiola ajimobi

Gbogbo idile Ajimobi lo n ṣelede lẹyin eeyan wọn, Sẹnetọ Abiola Ajimobi, nibi ayẹyẹ yii si ni ẹgbẹ ti Sẹnetọ ọhun wa ko to dagbere faye ti sọ pe ipa ti eeyan ko lee gbagbe laye ni Ajimobi ko laye awọn eeyan to mo iyi idari, iṣejọba daradara ati iwa ire inu eniyan.

Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimobi

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ karunlelogun oṣu kẹfa ọdun 2919 ni iroyin iku Ajimobi gbode kan lẹyin ti iroyin ni ọwọja arun Covid-19 to n ba finra baa gidi gan to si gba ibẹ lọ.

Ajimobi ni gomina akọkọ to dari ipinlẹ Oyo fun saa meji lerawọn to si jẹ pe lasiko to ku, o jẹ igbakeji adari ninu ẹgbẹ oṣelu APC niha Guusu.

Ajimobi ti wọn pe ni Aarẹ Ibadan naa pe aadọrin ọdun ko to kuro loke eepẹ.

Ninu atẹjade kan ti Olawale Sadare to jẹ oluranlọwọ pataki fun igbimọ amuṣẹya APC ni ipinlẹ Oyo fi sita, Oloye Akin Oke to jẹ alaga no laarin ọdun kan to kọja yii, o jẹ ipenija fun ẹgbẹ oṣelu naa tori aisi Sẹnetọ Ajimobi laarin wọn tori bo ṣe maa n ṣe asugba ohun gbogbo lapaa Guusu-Iwọ Oorun ati kaakiri Naijrira titi de ẹyin odi.

Aoran Abiola Ajimobi

Oríṣun àwòrán, Senetor Abiola Ajimobi

O ni ni ọdun mẹjọ ti oloogbe Ajimobi lo, "ko kan ṣe bii awọn aṣaaju bii Oloye Obafemi Awolowo, Bola Ige ati Alhaji Lam Adesina nikan, ṣugbọn o ṣe atunto ibi gbogbo fun anfani awọn iran to n bọ lẹyin rẹ ni".

Wọn bu ẹnu atẹ lu nkan to n ṣẹlẹ ninu oṣelu bayii lẹyin t Ajimobi ti ku pe ko dara to. Wọn ni awn eeyan n ko okiki alafia ati idagbasoke ti Ajimobi mu wa saye awọn ara Oyo nigba to wa nijoba.

Wọn ni fun idi eyi lawọn fi n yẹ ẹ si lẹyin iku rẹ.