Tope Alabi vs Yinka Alaseyori: Yinka Alaṣeyori fi ọ̀rọ̀ ìjínlẹ̀ púpọ̀ àiti omijé ṣàlàyé ìtumọ̀ Oniduro Mi

Yinka Alaseyori

Oríṣun àwòrán, Alaseyori

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Olorin ẹmi to ti di gbajugbaja bayii, Adeyinka Alaṣeyori ni iyatọ ti de ba aye oun lati igba ti ọrọọ pe kilode to pe Ọlọrun ni Oniduro Mi gbode kan gẹgẹ bo ṣe jade lati ẹnu agba olorin ẹmi Tope Alabi.

Yinka Aleseyori jẹ ki ilẹ ta sii diẹ ko tilẹ to fọhun rara pe ki awọn eeyan jẹ ki alafia jọba toripe iya ni Tope Alabi jẹ si oun.

Nibayii, o tun jẹ ki ilẹ ta sii daadaa to bẹ́ẹ to ṣe pe awọn agba ajihinrere ti da si ọrọ ọhun ti wọn ni ete Eṣu lati da aarin awọn olorin ẹmi ru ni amọ ki wọn tẹsiwaju lati maa gbe ogo Ọlọrun ga. Lẹyin eyi, Tope Alabi gangan ti pada dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan pe O kú ogun àjàyé Tope Alabi, odò Jodani lo ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjà yìí o! Àmọ́ rántí pé ... - Mike Bamiloye

Ẹwẹ, Yinka Alaseyori ti papa fi awọn ọrọ iṣiti ati ọrọ ijinlẹ ṣalaye ati akajuwe itumọ "Oniduro gẹgẹ bi orukọ to tọ to si yẹ fun Ọlọrun.

"Aa le duro ti alabagbe wa nileewosan fun odidi ọdun kan, aa tilẹ le ṣee foṣu kan tori ibi iṣẹ, ẹlomiran a fi ọmọ rẹ silẹ a tun pada wa sile wa ba a..."

Sugbọn ẹni ti o ki n kuro nidi ọrọ mi, ti ko ṣaṣiṣe kuro nidi ọrọ mi, ti ko ni o sun fii lẹ ko maa sun lọ ki wọn jii jii jii ti ko ni ji ki wọn lọ gbe e sinu saare, ki ni mo fẹ sọ fun un".

O ni nigba ti iwọ gangan n sun ẹni to duro ti ọmọ rẹ ki lo fẹ sọ fun un. Ngbati ọta rẹ n wa ni gbogbo igba ti o n sun, ẹni to n ba ẹ ṣaa laake lori, ki lo fẹ sọ fun un.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Ni Alaṣeyori ba tun kẹnu bọ orin pẹlu omije pe "bo jẹ pe eeyan ni, wọn a maa duro ki n jẹ ounjẹ pari, ko ṣe ẹni ti mo ti ṣẹ tẹlẹ ni.

Abi ki wọn maa duro ki n wọ aṣọ ti wọn ya mi lọ si ode ki wọn wa faa ya nita gbangba".

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ orin tuntun ti Yinka Alaseyori ti ṣe atunto orin Oniduro Mi yii gẹgẹ bo ṣe ni pe bo ba ti jẹ Ọlọrun ni o, ko tilẹ le binu ko si bi eeyan ṣe ṣẹẹ to, awọn Angẹli a tun maa yọ ni pe ki o maa pada bọ wa sọdọ Ọlọrun. "Ko si boo ṣe buru to, yoo tun maa duro de ọjọ ti waa pada wa, torinaa "Guarantor wa ẹ ma ṣe o!"

Ni kete ti iyi orin Oniduro Mi gbode kan ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni tọka si Yinka Alaseyori gẹgẹ bi ẹni to jẹ ki orin naa tan ka, ni imisi pupọ ti n wa sii lojoojumọ ti awn eeyan si rọ́ọ̀ṣì awọn orin rẹ witiwiti.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba