Back to sender charm kills 10 in Kwara: Wọ́n ní Okosi Musa àti Worugura Julin ló fún obìnrin kan ni PENNIA Bonnie ni gàá àwọn Fulani

Gomina

Oríṣun àwòrán, @Abdulrazak

Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tí tẹ àwọn méjì kan lórí aburú tó wáyé ní abúlé Biogberu ni Gwanara níjọba ìbílẹ̀ Baruten ìpínlẹ̀ Kwara.

Iṣẹlẹ yii níbi tí ènìyàn mẹ́waa tí jẹ́ Ọlọ́run nípè lẹ́yìn tí wọ́n mu àgbo ìbílẹ̀.

Iṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní abúlé kan lọ́jọ́ Eti tó kọjá ṣùgbọ́n ọjọ́ Isegun ni wọ́n tó mẹ́jọ́ lọ sí ọ̀dọ̀ ọlọ́pàá.

Àwọn tọkọ taya àti àwọn ọmọ wọn tó fi mọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ní ọ̀rọ̀ náà kàn.

Ìròyìn sọ pé ara ìlú méjì kan Okosi Musa àti Worugura Julin ni wọ́n fún obìnrin kan ni PENNIA Bonnie ni gàá àwọn Fulani ni Biogberu gẹ́gẹ́ bí òògùn fún ẹsẹ̀ tó ń dùn.

Wọ́n ni wọ́n gbáà nímọ̀ran bákan náà láti fún gbogbo ẹbí rẹ ki nǹkan tó ń ṣe máa bá má tàn ká àwọn ẹbí tó kù.

Àkọlé fídíò, Alhaja Rukayat Batimoluwasi Oniwaka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀
Ibudo igbokusi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ilorin: Èèyàn mẹ́wàá dèrò ọ̀run lẹ́yìn tí wọ́n mu àgbo fún ìtọ́jú egbò ẹsẹ̀ Musa n'Ilorin

'Òògùn ìtọ́jú egbò ni Musa pe àgbo tó fún mi, àmọ́ èèyàn mẹ́wàá ti kú lẹ́yìn tí wọ́n lò ó'

"Agbo ni wọn lawọn gbe wa fun iya mi ti ẹsẹ n dun, ṣugbọn eeyan mẹwaa lo kan agbako iku lẹyin ti wọn jijọ lo agbo naa".

Iroyin kayeefi ti o tun tẹ wa lọwọ ree lati ilu Biogberu ni Gwanara, ipinlẹ Kwara.

Ninu iṣẹlẹ yii la ti gbọ pe eeyan mẹwaa ninu mọlẹbi kan ti dero ọrun lẹyin ti ẹni tẹsẹ n dun kan ati awọn ẹlomiran ninu idile rẹ lo agbo.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara fi fidi ọrọ yii mulẹ, wọn ni arakunrin kan Ibrahim Bonnie lo wa fi ẹjọ iṣẹlẹ naa sun lagọ ọlọpaa Biogberu.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Gẹgẹ bi alukoro ọlọpaa Kwara Okasanmi Ajayi ṣe sọ, o ni Ibrahim sọ pe Okosi Musa ati Worugura Junlin ni wọn gbe agbo naa wa ba iya oun ti o ni egbo lẹsẹ.

Ibrahim ṣalaye pe wọn ni oogun iwosan egbo ni agbo yi jẹ ati pe ki mama rii pe awọn mọlẹbi rẹ naa mu ninu agbo yii ki aisan ọhun baa ma tan d'ọdọ wọn.

Ko pẹ si igba ti wọn lo agbo yii tan lawọn eeyan inu mọlẹbi yii ba bẹrẹ si ni ku lọkọọkan.

Alukoro ọlọpaa sọ pe ni meni meji, eeyan mẹwaa to fi mọ ẹni ti wọn ni ko fi agbo tọju egbo lo ti dero ọrun.

Okasanmi fi kun un pe Kọmisana ọlọpaa Kwara Mohammed Lawal Bagega ti ni ki iwadii bẹrẹ ni bonkẹlẹ.

Bẹẹ lo ni awọn ti fi awọn afurasi meji to gbe agbo naa wa si ahamọ ti wọn si ti n ran ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn.

O wa rọ awọn araalu paapa ara ilu ti iṣẹlẹ naa ti waye lati tọ awọn onimọ ilera lọ nigbakigba ti wọn ba ni ailera kankan.

Aworan yii jẹ ti ile itura Pavillion Hotel, Ayepe, ti wọn fi ẹsun kan ni oṣu Keji, ọdun 2021 pe o fi ẹrọ ayaworan sinu yaara awọn onibara

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Aworan yii jẹ ti ile itura Pavillion Hotel, Ayepe, ti wọn fi ẹsun kan ni oṣu Keji, ọdun 2021 pe o fi ẹrọ ayaworan sinu yaara awọn onibara

Saaju ni wọn ti ba oku ni iyara itura ni Ilorin:

Wọ́n bá òkú ọmọbìnrin nínú ilé ìtura ní Ilorin lẹ́yìn tí ọkùnrin tó gba yáàrá sálọ

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti kede oku obinrin kan ti wọn ri ni ile itura Premium Diamond Hotel, to wa ni adugbo Adewole nilu Ilorin.

Iroyin sọ pe ọkunrin kan to pe ara rẹ ni Adegboye James, to ni oun wa lati nọmba 12, Okelowo Street, Ede, nipinlẹ Osun, lo gba yara naa lọjọ kejidinlọgbn, oṣu Karun-un, ọdun 2021.

Amọ, o pada jade lọ, to si pada si ile itura naa pẹlu obinrin ti wọn pada ba oku rẹ ninu yara.

Ẹni to jẹ alamojuto ile itura naa, Olalekan Anafi, la gbọ pe o fi ọrọ to awọn ọlọpaa leti lẹyin ti wọn fi kọkọrọ mii ṣi ilẹkun yara naa.

Nigba ti wọn ko gburo ẹnikẹni lara awọn mejeeji ni ọjọ keji, ti wọn si ṣi ilẹkun ni wọn ba oku obinrin ọhun, ko to o di pe wọn mọ pe ọkunrin naa (Adegboye) ti kuro nile itura lai si ẹni to mọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Ajayi Okasanmi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba sọ pe iwadii fihan pe ayederu ni orukọ ati adirẹsi ti Ọgbẹni Adegboye James kọ silẹ nile itura Premium Diamond.

Bakan naa lo sọ pe gbogbo nkan ti wọn fi le da obinrin naa mọ tabi ṣawari ẹbi rẹ, bi foonu, ni ọkunrin naa ko salọ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

O fikun ọrọ rẹ pe ko si àpá tabi ẹjẹ lara obinrin naa.

Agbenuso ṣalaye pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, paapaa nipa yiyẹ ẹrọ ayaworan CCTV to wa nibẹ wo, botilẹ jẹ pe o ni ẹyin ni ọkunrin naa kọ si ẹrọ ayaworan.

Bakan naa lo tun kesi awọn araalu ti mọlẹbi wọn obinrin ba di awati lati ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, lati lọ si ẹka to n wadii iwa ọdaran ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol