Olonisakin, Buratai: Buhari kéde àwọn ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ọmọ ogun tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi aṣojú Naijiria nílẹ̀ òkèèrè

Oríṣun àwòrán, @others
Aare Buhari kéde Buratai ati Olonisakin gẹ́gẹ́ bíi aṣojú Naijiria sí Benin àti Cameroun
Minisita to n ri si ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, lo fun awọn ọgagunn naa ni iwe iṣẹ wọn tuntun lọjọru.
Wọn fun ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun tẹlẹ, ajagunfẹyinti Lt. Gen. Tukur Yusufu Buratai ni lẹta gẹgẹ bii aṣoju Naijiria si orilẹ-ede Republic of Benin.
- Àwọn lọ́balọ́ba nílẹ̀ Yoruba dalẹ̀ wa lórí àwọn ọmọ OPC mẹ́ta tí wọ́n tímólé láìṣẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ Iskilu Wakili - Ẹgbẹ́ OPC
- Wọ́n bá òkú ọmọbìnrin nínú ilé ìtura ní Ilorin lẹ́yìn tí ọkùnrin tó gba yáàrá sálọ
- Iléẹjọ́ tí dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ OPC tó mú Iskilu Wakili sílẹ̀ pé kí wọ́n máa lọ ní àlááfíà
- Ta ló gbé ìròyìn ikú ẹlẹ́jẹ̀ nípa Wòlìí SK Abiara, kí ní wọ́n sì ṣe fún un?
- Ilé ẹjọ́ ECOWAS pàṣẹ fún Naijiria láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter
- Ẹ̀wọ̀n ọdún méje gbáko ni adájọ́ sọ pé kí Farouk Lawan fi ṣara ridin!
Nigba ti ajagunfẹyinti Abayomi Gabriel Olonisakin to jẹ minisita eto abo tẹlẹri gba lẹta gẹgẹ bii aṣoju Naijiria silẹ Cameroon.
Lasiko ti wọn n kede ipo tuntun naa fun awọn eeyan ọhun, minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama ki wọn ku oriire, o si tun rọ wọn lati jẹ aṣoju Naijiria rere nilẹ okeere.
Nigba ti wọn n fesi, Buratai ati Olonisakin ṣeleri lati jẹ aṣoju rere fun Naijiria ati lati lo iriri wọn lẹnu iṣẹ ologun ni Naijiria lẹnu iṣẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gba.
Ọjọ kẹrin, oṣu Keji, ọdun 2021 yii ni Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ awọn eeyan mẹrin to jẹ ọga agba ileeṣẹ Ologun ana ṣọwọ sile igbimọ aṣfin fun fifi ontẹ lu.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo tapa si igbesẹ ọhun, awọn aṣofin buwọlu orukọ awọn mẹrẹrin naa lọjọ kẹtalelogun, oṣu keji kan naa.
Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ana, Ibok Ibias ati ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi ana, Abubakar Sadique ṣi n reti lati gba lẹta ti wọn.
- A kò gbọ́ pé Sunday Igboho fẹ́ ṣe ìwọ́de ní ìpínlẹ̀ Eko- Kọmisọ́nnà ọlọ́pàá
- Ṣé lóòtọ́ ni olè kan wọlè fipá bá ìyá 80 lòpọ̀ nípìnlẹ̀ Ondo?
- A ti fi páńpẹ́ ọba mú ènìyàn mẹ́ta lórí ìpànìyàn tó wáyé ní Iwo Road, Ibadan - Ọlọ́pàá
- Alága ìjọba ìbílẹ̀ Eti-Osa, Eko tí jádé láyé lẹ́yìn tó ṣe àìsàn
- Kò sí ìpínlẹ̀ tí ijọba mi kò tíì fọwọ́ bà sí rere- Ààrẹ Muhammadu Buhari
- Ẹranko àìmọ́ kan wọ Nàìjíríà, ó pa ènìyàn mẹ́rin ní Benue- ilé iṣẹ́ ọmọogun ni ìròyìn òfegè ni
- Pipa ní wọ́n gbọ́dọ̀ pa àwọn agbébọn tí wọ́n ń jí àwọn ènìyàn gbé, ẹ da ọ̀rọ̀ Sheik Gumi nù -Aisha Yesufu














