SK Abiara rumoured death: Ṣé ẹ mọ̀ npé onígbàgbọ́ ni wá, ohun táa ṣe fún oníròyin náà nìyìí

"Afi ki Ọlọrun dari ji awọn to n gbe iroyin aburu kiri pe mo jade laye!".
Oludasilẹ ijọ Christ Apostolic Church, Agbala Itura, Woli Samuel Abiara ti ni irọ patapata ati iroyin ofege lasan ni awọ́n iroyin ti awọn kan n gbe kiri nipa iku rẹ.
Ninu ọrọ ti ọmọ Woli Abiara, Woli Elijah Abiara to n gbe ni ilu Amẹrika sọ fun BBC Yoruba lori ẹrọ ibanisọrọ, o ni lootọ ni iroyin ọhun tan ka, lootọ si ni pe awọn gẹgẹ bii ẹbi ti fesi pe ofuutu fẹ́ẹ̀tẹ̀ irọ gbaa ni.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- Ohun tó dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wá ni láti yá owó fún ṣíṣe ojú pópó wá - Fashola
- Gómìnà ṣàbẹ̀wò sí àwọn tí ọlọ́pàá yìnbon lù l'Enugu, Ọ̀gá ọlọ́pàá ní ìwádìí gbọdọ̀ wáyé kíákíá
- Father's Day fa gbas-gbos láàrin Mercy Aigbe àti ọkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀, Gentry, ọkọ́ ní òun le tú àwọn àṣírí ìwà nọ̀bì rẹ̀ síta
- Ìgbẹ́jọ́ Kemisola Ogunniyi kò wáyé lóní, ó tún dọ̀la, ṣùgbọ́n... - Agbẹjọ́rọ̀
"Lootọ ni ọrọ naa, amọ oniroyin to kọ ọ ti wa tọrọ aforiji lọwọ wa, a si ti fi ọrọ sita lori eyi".
Woli Elijah nigba to n fesi boya ẹbi Baba Abiara dari ji ẹni to ṣe iṣẹ aburu yii abi wọn yoo ti ọrọ ofin bọ ọ bii ki wọn gbe e lọ ile ẹjọ o ni, "ṣe ẹ mọ pe onigbagbọ ni wa, a o ni ṣe gbogbo iyẹn. O ti tọrọ aforiji a si ti dari ji i".
Ninu atẹjade ti mọlẹbi fi sita, Wolii Abiara gbadura pe ki Ọlọrun dari ji awọn to wa nidii iroyin naa.
Alufa naa ni o ya ni lẹnu pe latọwọ oniroyin gaan to yẹ o maa sọ ootọ naa ni iru iroyin yii ti jade.
"Iroyin ofege ni eleyii o si ya ni lẹnu pe oniroyin lee gbe irọ sita lai ṣewadii. Oniroyin to jẹ pe o yẹ ka ba nidii iroyin otitọ o yẹ ko maa wa ninu iru iroyin irọ bayii".
O tẹsiwaju pe, "ọrọ yii ti kan kaakiri aye. Iroyin ofege kọ ni ọna lati ni eero pupọ to n ka iwe iroyin rẹ tabi tẹle ọ lori ayelujara. Nitorinaa, a pe fun ki iwe iroyin naa faa yo kuro patapata tabi ki o polongo aforiji rẹ lori iwe iroyin kan naa laarin wakati mẹrinlelogun ko maa baa ri oju ofin". Eyi ni atẹjade ti iroyin ni ẹbi Abiara fi sita.
Abiara ni Ajihinrere agba ni ijọ CAC Agbala Itura ti o si ni oun wa laye o, kokoko lara oun le.
Lọgan ti ohun ti wọn beere fun yii jade naa si oniwe iroyin naa lọ yọ iroyin aburu to jẹ irọ hun kuro to si tun polongo rẹ jade pe awọn ṣe aṣiṣe ni, awọn oniroyin naa si ti n gbe tuntun yii kiri.

Oríṣun àwòrán, kemiashefonlovehaven

Oríṣun àwòrán, kemiashefonlovehaven














