Fashola: Ohun tó dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé wá ni láti yá owó fún ṣíṣe ojú pópó wá

Oríṣun àwòrán, Google
Yíyá owó fún ṣíṣe ohun amúlùdún dára fún ètò ọ̀rọ̀ ajé Naijiria, mínísíta fún ọ̀rọ̀ iṣẹ́ àti ilé ìgbé Babatunde Fashola (SAN) lọ fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀.
Làsìkò to ń sọ̀rọ̀ níní ètò kan tí ilé iṣẹ́ ìròyìn NAN ṣe àgbékalẹ̀ ló ti ṣàlàyé pé orile de Nàìjíríà kò ní ṣe àṣeyọrí kankan tàbí ní ìlọsíwájú láì yáwó láti ṣe àwọn ohun amayederun.
"Fún ànfàní ara wa ni ìjọba ṣe yá àwọn owó kan tí wọ́n sì lo láti dé nǹkan mọ́lẹ̀ nítorí abala ti wọ́n ń lò ó fún rán ètò ìgbà ní ṣíṣe lọ́wọ́.
- 'Kò sí ẹni tó lè ní kí a má wá sí Èkó, iwọ́de òní pẹ̀lẹ́ kùtù la fẹ́ ṣe'
- End SARS, Kemisola Oguniyi: Láti 23/10/2020 ni Kemisola Ogunniyi ti dèrò ẹ̀wọ̀n nítorí ìwọ́de EndSARS tó fi wa bímọ sẹ́wọ̀n báyìí
- Mo ṣetán láti wọ inú igbọ́ lọ wa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jígbé- Gomina ìpínlẹ̀ Kebbi
- ''Oyún oṣù méjì ní Kemisola Ogunniyi gbé dé ọgbà ẹ̀wọ̀n, a sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ dáradára''
- Wo ìdí tí EFCC fi fẹ́ wádìí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun láti ọdun 2015 dí àsìkò yìí
"Èmi pẹ̀lú kò fara mọ́ kí ènìyàn má a yáwó láì nidi, ó gbọdọ̀ ni ìdí pàtàkì kí a tó yáwó.
Gẹ́gẹ́ bi Fashola ṣe sọ, àwọn orileede tó ti tojuubọ́ náà ṣe àgbékalẹ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé to gbó pọn láti ara owó yíyá ni.
Ó ní owó tí ìjọba àpapọ̀ yá láìpẹ́ yìí kò ní ṣe ìjàmbá fún ọjọ́ iwájú Nàìjíríà.
Fashola ni ìgbàgbọ́ àwọn amunisin tó sọ pé bí ènìyàn bá ń yá ìbànújẹ́ ẹni náà yóò pọ̀ sí àwọn òbí mi àti ìran wọn sọ pé kí a má yà owó.
Àwọn tó jẹ́ gbèsè julọ ni àwọn orileede tó tojuubọ́, wọ́n sì ni ètò ọ̀rọ̀ ajé to dára, wón ní ọkọ̀ ojuurin to rẹwà, pápákọ̀ òfuurufú tó dára àti àwọn ilé ìwòsàn tó dára.
Mínísítà fi kún pé owó iná lórí kikọ́ ojú pópó nìkan ti di bílíọ̀nù méjìdínlógún ni odun 2015 tí ó sì ti di irínwó bílíọ̀nù lọ́dún yìí.
Èyí bákan náà tí mú kí ọrọ̀ àti ànfàní isẹ pọ̀ sí, ó kéré tán ijoba ti pèsè isẹ àgbà ṣe tó dín díẹ̀ ni ẹgbẹ̀rún kan tí wọ́n sì ti gbé kọngila òpópónà kìlómítà ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá síta, ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ àkànṣe afárá ló ń lọ lọ́wọ́ àti àwọn àtúnṣe òpópónà marosẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà.
Fashola ni ààrẹ̀ Muhammadu Buhari ń farajì láti pèsè òun amayederun láti tí mú kí igbayegbadun derun sí.
Ó tún ṣàlàyé pé òpópónà marosẹ̀ Lagos-Ibadan àti afárá Niger kejì yóò parí kí ààrẹ tó kúrò nípò lọ́dún 2023.















