$500, 000 bribe: Farouk Lawan gbà ìdájọ ẹ̀wọ̀n ọdún méje lẹ́yìn ọdún mẹ́sán án tí ẹjọ́ tí wà níwájú adájọ

Farouk Lawan
Àkọlé àwòrán, Farouk Lawan

Ile ẹjọ giga ni olu ilu Naijiria, Abuja ti dajọ ẹwọn ọdun meje fun aṣofin tẹlẹ ri Farouk Lawan.

Idajọ yi ko si ṣẹyin ẹsun pe o fi ipo rẹ gẹgẹ bi alaga igbimọ ile to n ṣe iwadii lori ọrọ ẹkunwo epo rọbi labẹ ijọba igba naa ko owo jẹ.

Adajọ Angela Otaluka fi idajọ yi lelẹ lọjọ Iṣẹgun lẹyin to gbọ awijare gbogbo awọn tọrọ kan ninu ẹjọ naa.

Adajọ sọ pe kii ṣe ọrọ pe wọn fura si Lawan ni ẹjọ to wa nilẹ yi bi kii ṣe pe o beere fun abẹtẹlẹ miliọnu dọla mẹta to si gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta dọla.

O ni eronja iwa ajẹbanu n bẹẹ ninu ihuwasi Farouk eyi to han gbangba nitori ko sọ fun awọn agbofinro pe eeyan kan fẹ fi owo wa oju ire lọdọ rẹ.

Ṣaaju ni idajọ fọwọ da awijare ti Farouk mu wa pe ẹjọ naa ti gba asiko pupọ debi pe wọn n gbẹjọ naa fun ọdun mẹsan.

Aworan Farouk Lawan ati Femi Otedola

Ajọ to n gbogun ti iwa ajbanu ICPC lo wọ Lawan lọ si ile ẹjọ lẹyin ti fọnran fidio lu sita nibi to ti n gba owo abẹtẹlẹ lọwọ oniṣowo Femi Otedola.

Iwadii Lawan bẹrẹ lọdun 2012 lẹyin ti wọn fi ẹsun kan an wipe o lo ipo rẹ gẹgẹ bi alaga igbimọ iwadii ajẹbanu lori ọrọ kunwo owo epo rọbi ni Naijiria.

Ajẹbanu yi la gbọ nigba naa pe o wọ biliọnu dọla mẹfa.

Lasiko iwadii yi ni wọn fẹsun kan Lawan pe o f gba abẹtẹlẹ miliọnu mẹta dọla lọwọ gbajugbaja olokoowo Femi Otedola.