Ondo rape case: Àwọn ara Ondo lu olè, Emmanuel Joseph tó ń jí ǹkan lọ́wọ́ arúgbó sí ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run- ọ̀gá ọlọ́pàá Ikoro

iwa odaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iroyin to gba igboro kan ni Ondo bayii ni pe ẹni ọdun 35 tún fipá bá ìyá ẹni ọdun 80 lòpọ̀ nípìnlẹ̀ Ondo

Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tí mú ọkùnrin kan, Emmanuel Joseph ẹni ọdún márùnlelọ́gbọn tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó fipá bá ìyá ọgọ́rin ọdún lòpọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ondo

Wọ́n fẹ̀sùn kan Emmanuel pé ó gbà ojú fèrèsé ìyá wọlé lágbègbè Lotogbe ní ìjọba ìbílẹ̀ Ondo West tí ó sì mú àdá dání láti fi halẹ̀ mọ́ ìyá náà tí ó sì bá a sùn.

Ìròyìn sọ pé ó kó owó bákan náà ló kọ owó ìyá òun nigba ti iròyìn mìíràn sò pé ẹni a fẹ̀sùn kàn òun wọ inú ilé ìyá bí ẹni tó fẹ́ gba àgbo ni ẹ̀yìnkùlé ilé náà.

Ọ̀kan nínú àwọn tó jẹri sí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ tó pé ara rẹ̀ ni Julianah Owolabi ṣàlàyé pé ariwo ìyá ni àwọn ènìyàn gbọ́ tí wọn fi já ilẹ̀kùn ìyá wọlé tí wọ́n sì bá ọkùnrin náà ni ìhòòhò.

Owolabi ni ẹni a fẹ̀sùn kan yìí kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa mú nǹkan ìjà derùba àwọn ènìyàn ládùúgbò tí yóò sì má jàwọ́n lólè.

Ìròyìn tún fi ìdí rẹ̀ mú lé pé àwọn ọmọ ẹni tí ọ̀rọ̀ kàn yìí tí gbé ìyá wọn kúrò ní agbègbè náà nítorí ìtìjú.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Ẹni a fẹ̀sùn kan náà bẹ̀ ìyá àgbà náà láti fi ori jí òun nítorí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde ní ẹ̀wọ̀n ni. " Ẹ dárí jì mi, tí nkankan bá ti sọ pé kí n lọ jalè tàbí fi ipá bá ènìyàn lò pọ̀ máa ṣe ni, mo dá ara mi lẹ̀bi fún èyí tí mo se yìí.

"Mi o mọ nǹkan tó bá lè mi, wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fi mí sílé l'Ẹ́wọ̀n ni kí àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀ka idajọ tó lọ fún ìyanṣẹ̀lódì nítorí ìwà burúkú tí mò ń hù yìí. Ó ti pẹ́ tí mo ti ń ṣeé, ẹ jọ̀wọ́ ẹ dáríjìmí.

Kini Ileeṣẹ ọlọpaa fidiẹ mulẹ fun BBC lori iṣẹlẹ yii?

Agbenusọ ọlọ́pàá ni ìpínlẹ̀ Ondo Tee-Leo Ikoro ṣalaye fun BBC pe irọ pata ni pe Ole naa, Emmanuel ba iya agbalagba naa sun.

Ikoro ni pe nitootọ ni ole naa maa n ja awọn agbalagba lole to si maa n dẹru ba wọn lati gab nkan lọwọ wọn.

Àkọlé fídíò, End SARS: Kemi jáde níle láti lọ bá mi ra oògùn ni mo gbọ́ pé ọlọ́pàá ti gbée- Ìyá Kemisol

O ni pe nitootọ ni ọwọ awọn eeyan tẹ Ole naa tó si di pe wọn lu Emmanuel naa de bi pe o wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

O ni oun ko nii lọkan lati fipa ba iya arugbo naa sun bikose pe ki oun ja iya naa lole

Ọga ỌLọpaa ni pe ikọlu ni ẹsun naa kii ṣe ifipa ba arugbo lo pọ.

Ogun

Oríṣun àwòrán, others

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ẹni ọdún 40 tó fipá bá ìyá ọdún 60 lòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun

Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tí tẹ afunrasí kan ẹni ogójì ọdún Adesina Adebowale tó fipá bá ìyá ẹni ọgọ́ta ọdún lòpọ̀.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Agbenusọ ọlọ́pàá Ogun DSP Abimbola Oyeyemi sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́jọ́ ajé ṣàlàyé pé àwọn lépa ọkùnrin náà lẹ́yìn tí ọmọ ẹni tí ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí mú ẹjọ́ wá sí àgọ́ ọlọ́pàá Idanyin.

Gẹ́gẹ́ bi ó ṣe sọ, ó ní ọmọ ẹni tí iṣẹ̀lẹ̀ náà bá sọ pé ní nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ni afunrasí náà já ìlẹ̀kùn wọ ilé ìyá òun tó sì fi ipá bá lòpọ̀.

Lẹ́yìn èyí ni ọlọ́pàá dá àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ síta láti mú ọ̀daràn náà. "wọ́n lépa rẹ̀ wọn sì rí mú, bákan náà ni wọ́n ti tètè gbé ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

Agbenusọ ọlọ́pàá Ogun DSP Abimbola Oyeyemi " Ọ̀daràn náà jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni òun hu ìwàbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Oyeyemi ṣe sọ.

O tún ṣàlàyé pé Kọmísọ́nà ọlọ́pàá Edward Awolowo Ajogún tí ni kí wọ́n gbé ọ̀daràn náà lọ sí ẹ̀ka CIID fún ìwádìí àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbẹ́jọ́