Michael Usifo Ataga: Chidinma jẹ́wọ́ bó ṣe pa Usifo Ataga tó ni iléeṣẹ́ Super TV l'Eko

Oríṣun àwòrán, Usifo Ataga
Iroyin to bọ si ọwọ wa ni yajoyajo sọ pe ọwọ palaba ẹni to pa olowo nni ati oludasilẹ ileeṣẹ amohunmaworan Super TV, Usifo Ataga lagbegbe Lekki ni Eko ti sẹgi.
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko gba Chidinma Adaora Ojukwu mu to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun to tun jẹ akẹkọọ fasiti ilu Eko.
Kọmisọna ọlọpaa Eko Yinka Odumosu ni funra Chidinma lo jẹwo pe oun loun pa gbajugbaja olowo naa ni Lekki. Odumosu tun fi kun un pe Chidinma ọhun ṣi n kẹkọọ ni fasiti Eko.
Iroyin sọ pe wọn tun ti mu ẹni to ni ile ti wọn ya gbe nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ. Bakan naa lo ni wọn ti gbegi di apo asunwọn owo Ataga ko ma baa si gbigba owo jade nibẹ mọ tori awọn to n lo anfani iku aitọjọ rẹ lati fa owo ninu akanti naa.
Ẹ wo bí olówó 'billionaire', Usifo Ataga ṣe kú ikú òjijì ní Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọ wi pe ipinlẹ Eko ni gbajugbaja baba ọlọla, Micheal Usifo Ataga ti wọn ti n wa fun ọjọ diẹ sẹyin ti ku.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni obinrin kan ti o fi fẹsẹ fẹ lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn gbagbọ wi pe o pa Micheal Ataga to jẹ adari ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Super TV lẹyin ti wọn ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ ni Ọjọbọ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu lasiko to n ba BBC Pidgin sọrọ ni ile igbe kan ni agbegbe Lekki Phase 1 ni ilu Eko ni iṣẹlẹ naa ti waye.
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Dino Melaye fi ọkọ Rolls Royce bùgá lórí Instagram, ni oníṣòwò ọkọ́ bá ní kó wá san gbèsè owó ọkọ̀ tó jẹ́ òun
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà
- Women Life saver car: Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ yì ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀ aláboyún àtọmọ ọwọ́ lá ní Jigawa
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
Bawo ni iṣẹlẹ iṣekupani Usifo Ataga ṣe waye ni ipinlẹ Eko?
Ohun ti iwadii wa gbe jade ni wi pe arakunrin Micheal Usifo Ataga pẹlu obinrin naa wa si ileegbe naa ni Ọjọ Isinmi.
Amọ ni Ọjọbọ lo yẹ ki arakunrin naa lọ si Abuja nibi ti awọn mọlẹbi rẹ wa ti wọn ti fẹ ṣẹ ayẹyẹ Ọjọ ibi aadọta ọdun fun un.
''Amọ ibanujẹ lo jẹ wi pe ko jade ni ọjọ naa, ti wọn si ti ilẹkun pa, amọ lẹyin ti wọn ja ilẹkun naa ni wọn ba oku rẹ nilẹ.''
''Sokoto penpe nikan lo wa ni ara Michael Osifo Ataga nigba ti wọn ba ninu agbara ẹjẹ''

Oríṣun àwòrán, Michael Usifo Ataga
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii fihan pe obinrin ti o ṣeeṣe ko ṣekupa a naa sọ fun wi pe ara ilu oyinbo ni oun nigba to pada baba olowo naa.
Iroyin sọ wi pe Ataga to n gbe ni Banana Island ni ipinlẹ Eko ni awọn ọrẹ rẹ kegbare pe o di awati ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ kẹtala, Osu Kẹfa, ọdun 2021.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni titi di asiko yii wọn ṣi n wa obinrin naa, to si mu ẹrọ ilewọ oloogbe naa ati ATM rẹ lẹyin ti iṣẹlẹ naa waye.
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Mo kú tì, nítorí pé àsìkò mi kòì tó láti padà sí ọ̀run- Kunle Ologundudu
- O kú ogun àjàyé Tope Alabi, odò Jodani lo ṣẹ̀ṣẹ̀ là kọjà yìí o! Àmọ́ rántí pé ... - Mike Bamiloye
- Ṣé lóòtọ́ ni ilẹ̀ America ti bẹ̀rẹ̀ 'visa lottery padà fún àwọn ọmọ Naijiria? Wo àlàyé níbí
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
''O ṣoro diẹ lati tọpasẹ obinrin naa nitori ile igbe Airbnb ni wọn jọ wa fun bi ọjọ mẹta si mẹrin nitori kani ile itura ni a ni ẹrọ CCTV ti wọn le fi tọpaṣẹ rẹ.
''Ohun ti a mọ nipa obinrin to ṣeeṣe ko ṣiṣẹ ibi yii ni pe o gba ọgọọrọ owo ninu ATM ọkunrin naa, amọ a ti gbegidi ATM naa ti ko si le e lo o mọ.''
''A ṣi n wa obinrin naa amọ a ko ni iroyin kankan nipa obinrin naa, ẹni ti a mọ wi pe o le e tọpaṣẹ rẹ ni ẹni ti wọn gba ile lọwọ rẹ ati apo iṣuna ti wọn fi san owo osu fun un.''
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa fikun pe ọkọ bọgini Range Rover ti ọkunrin naa wa de ibi ṣi wa ni ikawọ awọn ọlọpaa bayii.
Tani Michael Usifo Ataga to di oloogbe?
Ki o to di oloogbe, Micheal Usifo Ataga ni CEO ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ Super Network Limited lati ọdun 2014.
Michael ni iyawo ati ọmọ ti wọn wa ni ilu Abuja.
Ataga ti wọn da ẹmi legbodo ni ẹni aadọta ọdun lọ si ileewe Fasiti ti ilu Benin laarin ọdun 1988 si ọdun 1995.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
- Timothy Obadare ìránṣẹ́ Ọlọ́run to fọ́ lójú ìta ṣùgbọ́n tó ríran jù ọ́pọ́ wòlíì lọ
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
- Ọwọ́ tẹ ọmọdébìnrín tó jí ara rẹ̀ gbẹ́ nítorí ìyá rẹ̀ ní kó lọ kọ́ ẹ̀kọ́ láti ṣe dókítà


















