751 unmarked graves found: Bí wọ́n ṣe rí ọ̀pọ̀ sàárè okú nínú ọ̀gbá iléẹ̀kọ́ agbo ilé kan

Awọn eeyan ko bata ọmọde jọ lati daro ati lati ṣeranti awọn to ku

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan ko bata ọmọde jọ lati daro ati lati ṣeranti awọn to ku

Ilu iṣẹmbaye kan ni wọn ti ṣawari awọn saare oku to le ni ẹẹdẹgbẹta abọ ni ori ilẹ ileewe agbo ile Saskatchewan ni Canada.

Ajọ First Nation to nlo awọn darandaran ni Canada ni ohun tuntun yii jẹ eyi ti wọn ṣẹṣẹ gbọ titi di akoko yoo ni Canada.

Eyi ṣẹlẹ lẹyin ti wọn tun ṣẹṣẹ ri oku akẹkọọ igba le mẹẹdogun niru ileewe agbole yii ni Columbia.

Itẹ oku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Sàárè òkú 750 dédé wú jádé níléẹ̀kọ́ agbo-ilé kan, ìlú dàrú!

Ileẹ̀kọ́ Marieval India Residential School ti wọn ti ṣaadede ṣawari awọn iboji oku yii ti wa lati ọdun 1899 titi di 1997 ti wọn ti wa gbe e lọ si ibudo mii ni apa Guusu- Ila Oorun Saskatchewan.

O jẹ ọkan lara awọn ileẹ̀kọ́ to le ni aadoje ti wọn n gbe nibẹ eyi ti ijọba Canada atawọn adari ẹsin pọn ni dandan ni ọọdunrun kọkandinlogun ati ogun tori eredi ati fa awọn ọdọ ilu mọ ile.

Itẹ oku

Oríṣun àwòrán, Tobias Titz

O to ẹgbẹrun mẹfa ọmọ ileẹ̀kọ́ to ku lasiko ti wọn n lọ awọn ileẹ̀kọ̀ ọhun tori idoju kọ ilera ninu ileẹ̀kọ̀ naa, ọpọ igba ni wọn n ko awọn ọmọ sinu ile ti wọn o kọ daadaa

Bẹẹ, ile naa ti oru gbigbona n ṣe hi-hii ati awọn nkan eelo to kun fun idọti.

Ko tan sibẹ, fifi lilu ati ilọkulọ ibalopọ lọ awọn ọmọ ọlọmọ lo mu ki awọn to ku sa mọ awọn to n dari ileẹ̀kọ́ to fẹ ba wọn lopọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

"Wọn jẹ ki a ro pe a ko ni ẹmi rara," ọkan lara awọn akẹkọọ to moribọ, Florence Sparvier sọ fun awọn oniroyin l'Ọjọbọ.

"Wọn n tẹ wa ri gẹgẹ bi eniyan torinaa a kọ ẹkọ lati ma naani tabi fẹran ara wa".

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Loṣu to kọja ni awọn darandaran bẹrẹ si ni lo awọn ohun elo to lee f ilẹ tutu lati fi wa awọn saare ti ko si nigboro ilu yii jade ni Saskatchewan.

Awọn darandaran naa ṣe apejuwe awari tuntun yii gẹgẹ bi eyi to ba ni lẹru jọjọ to si ja ni laya".

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Perry Bellagarde to jẹ oloye agba ile aṣofin wọn ṣapejuwe awari ti wọn ṣee yii gẹgẹ eyi to ba ni lẹru ṣugbọn o ni ko ya oun lẹnu.

"Mo ro gbogbo ara Canada lati gbaruku ti ajọ First Nation lasiko ti wọn n koju eyi".

Laarin ọdun 1863 ati 1998, o le ni ẹgbẹrun lọna ogoje ọmọ ilu ti wọn gba lọwọ awọn obi wọn lati ko lọ si awọn ileẹ̀kọ́ naa.

Àkọlé fídíò, Alhaja Rukayat Batimoluwasi Oniwaka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀

Wọn kii saba jẹ ki awọn ọmọ naa sọ ede abinibi wọn tabi dan aṣa wọn wo, ti wọn si n fiya ati ipa jẹ ọpọ ninu wọn.

Akọsilẹ wa fihan lọ̀dun 2008 pe ọpọ awọn ọmọ ni ko pada sọdọ obi wọn tabi ilu wọn.

line