Nigerians in Oman: Ìgbe àwọ́n ọmọ Nàìjíríà tó wà ní Oman tú àṣìrí igbèkùn tí wọ́n wà lọ́wọ́lọ́wọ́

Abike Dabiri-Erewa, awọn ọmọ Naijira ni Oman

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri-Erewa

Nkan bii aadọrun ọmọ Naijria to n gbe ni orilẹede Oman ni awọn ti ko si wahala bayii tori pe wọn ko ribi ṣe atunṣe iwe irina nigba ti iye saa ti ofin fun wọn lanfani lati lo pe paapaa lasiko yii ti orilẹede naa wa labẹ ofin isede latari Covid-19.

Ninu iwadi kan to ṣe pẹlu BBC, Abdulkadir Abdulwahab ni ọpọ awọn gan lo wa ni bebe ki ati padanu iṣẹ ti wọn n ṣe lawọn ileeṣẹ lorilẹede naa tori pe wọn o ni iwe igbelu.

Gẹgẹ bi Abdulkadir ṣe sọ iṣẹlẹ yii ti sọ wọn sinu ọpọlọpọ hila-hilo tori aini iwe igbelu tabi iwe irina ti saa to yẹ ki wọn loo fun ṣi ku lee ko wọn si wahala.

Àkọlé fídíò, 'Mo fọ kọ́mú, pátá, ògiri ilé lórí 200,000 láìlèfọhùn lórílẹ̀èdè Oman'

"A n ṣiṣẹ takun takun tori mọlẹbi wa ni, ẹ ran wa lọwọ, a wa ninu wahala o!"

O ni ajakalẹ arun Covid-19 ti mu ki iṣoro awọn buru jai sii ati wi pe oniruuru orilẹede lo ni ofin ti wọn gbe kalẹ lati koju itanka arun naa.

"Ọpọ ninu wa lo ro wi pe aaye gba wa lati rinrinajo jade lọhun ka tun pada wọle, bii ka lọ si Najiria ka pada lọ Oman ṣugbọn ni bayii gbogbo ọna lo ti di pa mọ wa".

Keyframe #1

O ṣalaye pe Naijiria ti wa lara awọn ibi aiwọ lagbaye. "Ẹnikẹni to ba si lọ si Naijiria ko lee pada wọ ibi mọ".

Amọ, o ni ofin yii ko kan awọn oṣiṣẹ Naijiria to wa ni ileeṣẹ Naijiria lọhun. "Ko si bibẹgi dina tiwọn lati rinrinajo pada wọ Oman lati maa ṣiṣẹ fun awa ọmọ Naijira".

Ẹwẹ, ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa lẹyin odi sọ pe awọn ko mọ rara nipa ohun ti wọn n la kọja nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ naa sọ fun BBC pe awọn ti gba ẹsun ti awọn ọmọ Naijiria kan fi ranṣẹ lati Oman.

Ọga agba ajọ naa, Abike Dabiri Erewa ba ọfiisi to n ṣeto iwe irina sọrọ ati minisita to n ri si ọrọ abẹle lori ọrọ iṣoro ti wọn n koju pẹlu erongba lati ran awọn ọmọ Naijiria to n koju iṣoro aini lorilẹede miiran.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Ààrẹ Buhari, ẹ̀yin gómìnà ìpínlẹ̀ Yorùbá, ẹ rántí wa ní Oman, àwọn ọmọ