Martial arts school fire: Èèyàn 18 tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ ọmọ́dé ló jóná, wo bí ọ̀pọ̀ ọmọdé ṣe tún farapa

Oríṣun àwòrán, ALBERT GONZALEZ FARRAN
O kere tan eeyan mejidinlogun lo ti gbẹmi mi ti awọn bii mẹrindinlogun si farapa yanayana lẹyin ti ina nla ya wọ inu gba ileẹkọ kan ti wọn ti n kọ nipa ija aabo ara ẹni ti oloyinbo n pe ni Martial Arts eyi ti ija Kongfu jẹ ọkan lara wọn.
Ọpọlọpọ awọn to fara gba ninu ijamba ina ọhun ni iroyin ni ọmọde ni wọn ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun meje si mẹrindinlogun ti wọn ngbe ninu ọgba ileẹkọ ti wọn ti nkọ ija yii, iyẹn Shenxing Martial Arts Centre to wa ni ẹkun Henan lorilede China.
Ina yii bu jade lowurọ kutukutu ọjọ Ẹti ti wọn si ti ribi pa , awọn alaṣẹ labẹle lo s eyi ṣugbọn ko han gedegbe ohun to ṣokunfa bi ina naa ṣe bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, FEDERICO SCOPPA
Irufẹẹ iṣẹlẹ ijamba ina aburu bayii ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ ni China eyi to si ni ilana idaabo bo ara ẹni kekeke tabi ti ko kunwọ to.
Gẹgẹ bi atẹjade ijọba Zhengcheng, ijọba ti fi panpẹ ofin mu eeyan to jẹ alakoso ileẹkọ ija naa.
Awọn oṣiṣẹ ijọba sọ fun ileeṣẹ iroyin Beiing Toutiao pe mkan bii akẹkọ mẹrinlelọgbọn to n gbe ninu ọgba ibudo ija naa lo wa nibẹ nigba ti ina ọhun burẹkẹ ni nkan bii ago mẹta akoko tiwọn lọhun.
Lọgan ni wọn ti gbe awọn ọmọ to farapa digba digba lọ sileewosan. Awn obi tawn oniroyin si ba sọrọ sọ pe wọn ko fun awọn ni alaye kankan koda wọn ko tii jẹ́ ki awọn ri awọn ọmọ.
Kà nípa ìṣẹ́dá àwọn tí kíní abẹ́ wọn ò dúró tẹ́yin olóyìnbò ń pè ní "Paedophile" àmọ́ n'ílànà ìṣẹ̀ṣe

Oríṣun àwòrán, FEDERICO SCOPPA
"Ni Zhenxing, loju ọjọ lawọn ọmọ maa n kọ ẹkọ ija martial arts wọn si tun n gbe nibẹ lalaalẹ. Mi o mọ ohun to ṣokunfa ina naa", ohun ti baba ọmọ ọ̀dun mẹsan kan to moribọ sọ ree.
Obi mii tun sọ fun ileeṣẹ iroyin Reuters pe "wọn ko gbogbo iroyin ati alaye pamọ fun eeyan".
Bi ẹ ba ti n gbọ Shaolin Temple, Ilu Henan ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ lo wa ibẹ si ni wọn mọ gẹgẹ bii ilu ti wọn ti bi imọ ẹkọ ija martial arts ni China nibi ti ọgọọrọ akẹkọ ti n k nipa ija Kongfu.

Oríṣun àwòrán, Cancan Chu















