Sheikh Gumi: Irọ́ ni pẹ DSS fi ìwé pè mí tàbí fi ọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò

Gbajugbaja ẹlẹsin Islam to fi ilu Kaduna ṣe ibugbe, Sheikh Ahmad Gumi ti sọ pe irọ ni iroyin to tan kalẹ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi iwe pe oun fun ifọrọwanilẹnuwo lori ọrọ kan ti oun sọ lodi si ileeṣẹ ologun Naijiria.
Gumi lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin isin Jumat ni Kaduna.
O ni ijọba Naijiria mọ si gbogbo akitiyan oun lati ba awọn janduku sọrọ ninu igbo ati pe ko si igba kankan ti oun lọ ba awọn janduku naa sọrọ ti ijọba ko mọ si.
- Òní ni ìwọ́de Yoruba Nation yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara
- NDLEA mú dókítà àti sọ́jà lórí ẹ̀sùn títà egbòogi olóró
- Ìwé ẹ̀rí àyẹ̀wò oògùn olóró yóò di dandan fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gbé'yàwò láìpẹ́- Buba Marwa NDLEA
- Ọlọ́pàá tó tẹ George Floyed lọ́rùn pa ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún àti oṣù mẹ́fà he l'Amẹrika
Sheikh Gumi ni "Mo fẹ sọ ni gbangba pe ko si ẹnikẹni to fi iwe pe mi tabi fi ṣikun ofin mu mi."
"Ko si igba ti mo ba n lọ sinu igbo lati ba awọn janduku ni ijiroro ti awọn agbofinro kii tẹle mi lọ lati daabo bo mi."
"Awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹmuyẹ DSS, awọn lọbalọba atawọn adari awọn Fulani maa n tẹle mi lọ sinu igbo naa, mi o tii da lọ ri."
Gumi sọ siwaju si pe oun ko fi igba kankan sọrọ kobakungbe nipa ileeṣẹ ologun ri ninu ifọrọwerọ lori ẹrọ amohunmaworan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ko fi ẹsun kan ileeṣẹ ọmọ ogun ri lori afẹfẹ.
Ṣaaju ni ọọfisi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti kọkọ sọ pe awọn ti fi iwe pe gbajugbaja ẹlẹsin Musulumi naa.
Agbẹnusọ ajọ ọhun, Peter Afunnaya sọ pe lootọ ni awọn fi iwe pe Gumi nitori ko si ẹni ti awọn ko le fi iwe pe ti ọrọ ba kan irufẹ ẹni bẹẹ.
Bo tilẹ jẹ DSS ko sọ ni pato eredi ti wọn ṣe fi iwe pe Gumi, ṣugbọn awọn eeyan kan ni igbesẹ ọhun ko ṣeyin awọn ọrọ ti Gumi n sọ lori iwa janduku ni Naijiria lẹnu ọjọ mẹta yii.
- Ẹ gbà wa o! Ìwé ìrìnà àti ìwé ìgbélùú wa ní Oman ti "expire", wọ́n tún ní Nàìjíríà ti di ibi àìwọ̀
- Kà nípa ìṣẹ́dá àwọn tí kíní abẹ́ wọn ò dúró tẹ́yin olóyìnbò ń pè ní "Paedophile" àmọ́ n'ílànà ìṣẹ̀ṣe
- Iyabo Ojo, mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha ní báyìí tí ọ̀rọ̀ ti dé iwájú mi - Adájọ́ Toyin Taiwo
- Ọ̀rọ̀ wo ni Sheikh Gumi sọ tí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ní kó wá ṣàlàyé ara rẹ̀?
- Iyabo Ojo, mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha ní báyìí tí ọ̀rọ̀ ti dé iwájú mi - Adájọ́ Toyin Taiwo
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣeyin?
Ọ̀rọ̀ wo ni Sheikh Gumi sọ tí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS ní kó wá ṣàlàyé ara rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, @Gumi
Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orileede Naijiria DSS ti kesi olori ẹsin Islam kan Sheikh Gumi lati wa ṣalaye ara rẹ lori awọn ọrọ kan to sọ.
Ni Ọjọbọ ni wọn fiwe pe to si ti yọju si wọn ni ọfisi wọn to wa ni ilu Kaduna .
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan ti agbẹnusọ Sheikh Gumi Tukur Mamu ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin VOA Hausa lo ti fidi ọrọ yi mulẹ.
Tukur sọ pe lootọ ni Gumi dahun si ipe awọn ileeṣẹ ọtẹlẹmuye nitori ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise TV.
Ki gaan lọrọ ti Gumi sọ
Ọrọ Gumi to sọ ni idahun si ibeere lori eto naa ni pe awọn ọmọ ogun Naijiria n lẹdi apo pọ pẹlu awọn janduku ajinigbe to n da omi alaafia Naijiria ru.
Nkan ti Gumi sọ yi jẹ nkan ti ko dun mọ ileeṣẹ ọmọ ologun ninu ti wọn si fesi pada pe ọrọ to sọ jẹ eleyi to le da wahgala silẹ to si jẹ ibanilorukọ fawọn.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ologun Ọgagun Onyeama Nwachukwu buwọlu, o ni awọn ọmọ ologun lo fẹmi wọn lelẹ lati wa awọn akẹkọọ FGC Yauri ti wọn ji gbe.

Oríṣun àwòrán, Others
O ni lootọ lawọn ko le maa tọrọ aforiji fawọn alaburu ninu ọmọ ologun ṣugbọn awọn ko le faaye gba ki eeyan maa lẹdi apo pọ pẹlu awọn ọta orileede.
Agbẹnusọ Sheikh Gumi sọ pe ileeṣẹ iroyin to gbe ọrọ sita lo yi ọrọ Gumi pada. O ni ninu ifọrọwanilẹnuwo ti Gumi ṣe, ko dẹbi kankan ru ileeṣẹ ologun ninu rẹ.
O wa kesi awọn ileeṣẹ amounmaworan Arise Tv ki wọn satunse ọrọ naa ni kiakia.














