George Floyed: Ilé ẹjọ́ sọ Derek Chauvin sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún àti oṣù mẹ́fà

Derek Chauvin

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọlọpaa alawọ funfun ti wọn fẹsun ka pe o tẹ ọkunrin alawọ dudu, George Floyed, lọrun pa niluu Minneapolis, lorilẹ-ede Amẹrika ti ri ẹwọn ọdun mejilelogun ati oṣu mẹfa he.

Adajọ to gbọ ẹsun naa sọ pe ọlopaa ọhun, Derek Chauvin, jẹbi nitori bo ṣe ṣi ipo rẹ gẹgẹ agbofinro lo lasiko ti iṣẹlẹ naa waye lọdun to kọja.

Oloogbe Floyed dero ọrun lẹyin ti Chauvin tẹ ẹ lọrun mọlẹ fun iṣẹju mẹsan an gbako.

Eyii lo mu ki Chauvin di ẹni to n kawọ pọn rojọ niwaju adajọ nibi to ti sọ pe oun ko mọọmọ gba ẹmi lẹnu oloogbe ọhun.

Yatọ si pe Chauvin foju bale ẹjọ, wọn tun fi ofin de pe ko gbọdọ fi ọwọ kan ibọn tabi ohun ija kankan mọ titi ayeraye.

Floyd family

Oríṣun àwòrán, Reuters

Yatọ si Cahuvin to ri ẹwọn he yi, awọn akẹgbẹ rẹ mẹta miran ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn tun foju bale ẹjọ lori ẹsun pe wọn fi ẹtọ Floyed labẹ ofin dun un.

Ẹwẹ, awọn mọlẹbi Floyed ti sọ pe inu awọn dun si idajọ ile ẹjọ naa ati pe o tẹ awọn lọrun.

Ṣugbọn awọn kan lara awọn ẹbi naa n fẹ ki afurasi ọhun ṣewọn fun ogoji ọgoji ọdun o kere tan.

Aburo oloogbe naa, Bridget Floyed sọ fun awọn akọroyin pe "Idajọ yii fi han pe ijọba ti bẹrẹ si n fi ọwọ gidi mu ọrọ bi awọn ọlọpaa ṣe n fi iya jẹ araalu lọna aitọ, ṣugbọn o ku nibọn n ro."

Nigba to n sọrọ idajọ naa, Aarẹ ilẹ Amẹrika, Joe Biden ni idajọ naa lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Àkọlé fídíò, Ijaw Paternity test: Mọ́ síi nípa ìgbàgbọ́ àwọn Ilaje nípa ọmọ ọkọ àti ọmọ àlè