Ogun Auto Crash Robbers: Ọwọ́ tẹ adigunjalè mẹta nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ogun

ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, @NPF

Àwọn afunrasi adigun jalè mẹ́ta kan ní ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun tẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú lẹ́yìn tí wọ́n ni ìjàmbá ọkọ̀.

Ìròyìn sọ pé àwọn afurasí náà ń sá lọ pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Camry tí wọ́n gbà lójú ìbọn lọ́wọ́ ẹnìkan ni ìpínlẹ̀ Ondo.

Agbenusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun DSP Abimbola Oyeyemi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nínú àtẹ̀jáde kan n'ilu Abeokuta lọ́jọ́ru

Nínú àtẹ̀jáde náà, Oyeyemi ni àwọn afurasí náà ń bọ̀ láti Ondo wọ́n sì ń lọ sí ìpínlẹ̀ Eko, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé Ode Remo, nítorí bí wọn ṣe ń wakọ̀ ni ìwàkuwà wọ́n kọlu afárá kan ni ọkọ̀ wọ́n bá tàkìtì.

Àtẹ̀jáde náà sọ báyìí pé : Àwọn ènìyàn mẹ́ta tó wà nínú ọkọ̀ náà ló farapa ni onírúurú ọ̀nà tí àwọ́n ọlọ́pàá Ode Remo sì sáré gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn

Àkọlé fídíò, Fisayo Amodemaja: Nínú eré 'Children Day' ní Sọ́ọ̀ṣì ni Abebi ti bẹ̀rẹ̀ eré ṣisṣe- Bukola

"Ìgbà tí wọ́n wà ní àgọ́ ọlọ́pàá ni ìròyìn tẹ DPO àgọ́ ọlọ́pàá Ode Remo lọ́wọ́ pé wọ́n jí mọ́tò tí wọ́n fi ní ìjàmbá ọkọ̀ lójú ìbọn ni wọ́n gbáà lọ́wọ́ ẹni tó nii.

"Bí ọlọ́pàá ṣe gbọ́ èyí ni DPO ni kí wọ́n fi wọ́n sí àhámọ́ nínú ilé ìwòsàn náà.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di

Ẹni tó ní ọkọ̀ náà wá láti ìpínlẹ̀ Ondo, ó sì ṣàlàyé pé àwọn márùn-ún ni àwọn ọ̀daràn náà tí wọ́n sì múra bí ọlọ́pàá, lẹ́yìn náà ni wọ́n wọ́ òun sọ̀kalẹ̀ nínú mọ́tò lójú ìbọn tí wọ́n sì gbé mọ́tò lọ".

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà tó pé ará rẹ̀ ni Emeka John padà kú lásìkò to ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Àwọn méjì tó kù Sunday Emmanuel àti Idris Ibrahim ni Kọmísọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun Edward Awolowo Ajogún tí ni kí wọn fi wọ́n sọwọ́ ẹ̀ka CIID kí wọ́n tó gbé wọ́n lọ́ sì ìpínlẹ̀ Ondo láti lọ ṣe ẹjọ́ wọn.