Yoruba Nation: Ààrẹ Buhari ṣèlérí láti buwọ́lu àtúntò Naijiria tí Ilé Aṣòfin bá ti buwọ́lù ú

Oríṣun àwòrán, @NigeriaGov
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni oun ko ni wẹyin wo lori ọrọ atunto orilẹede Naijiria ni kete ti Ile Igbimọ aṣofin ba ti buwọlu u, ti wọn si gbe wa si iwaju oun.
Aarẹ Buhari sọ eyi nigba ti Adari Ajọ Ijaw National Congress (INC),Ọjọgbọn Benjamin Okaba ati awọn alabaṣiṣẹ rẹ ṣe abẹwo si aarẹ Buhari ni ọfisi rẹ ni Abuja.
Lasiko ijiroro naa lori atunto orilẹede Naijiria ni aarẹ Buhari sọ wi pe oun ṣẹtan lati buwọlu atunṣe lori eto atunto Naijiria ti ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999 fi aye gba.
- Kó sí ààyé fún ìdíbò ''Referendum'' nínú Ìwé Òfin Naijiria, dídádúró ilẹ̀ Yoruba Nation yóò nira- Amòfin
- Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń ṣelédè lẹ́yìn Ajimobi, èrò wọn ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀!
- Èèyàn kan ti kú, 99 di àwátì lẹ́yìn tí ilé alájà méjìlá wó lulẹ̀ l'óru
- Ọmọ ọdún méje ni mo ti ń digunjalè, ogun ìdílé ló fàá, afurasí ṣàlàyé l'Ondo
- Ẹyìn tẹ ń gba ojú VPN wọ Twitter, ẹ kò ṣé mí, ará yín lẹ̀ ń ṣé - Lai Mohammed
Aarẹ Buhari ni Ile Igbimọ Asofin lorilẹede Naijiria lo laṣẹ lati ṣe atunto, Naijiria to si ni wọn ti pari ijiroro lori rẹ ni awọn ẹkun si ẹkun ni Naijiria.
''Ni wẹrẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin ba ti pari ijiroro lori rẹ ni oun yoo buwọlu lu u nitori oun ko ṣetan lati da wọ atunto orilẹede Naijiria duro.''
Amọ ọrọ ti aarẹ sọ naa tako eleyii to sọ ni asiko ni asiko ayẹyẹ Kudirat Abiola Sabon Gari Peace Foundation to waye ni Zaria, Kaduna nigba ti wọn bere lọwọ rẹ nipa atunto Naijiria to si sọ wi pe kini wọn n tun to ni Naijiria.
Nibayii, awọn to n pe fun atuntọ orilẹede Naijiria yoo ni igbẹkẹle pe aarẹ Buhari yoo ṣe ohun to tọ ni kete ti wọn ba ti gbe iroyin naa wa si iwaju rẹ.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ ẹni méjì tó lọ́wọ́ nínú àgbo tó pa ẹni mẹ́wàá ní Kwara
- Wo àwọn ìlànà tí ó máa tẹ̀lé láti wo èsì ìdánwò 2021 Jamb UTME rẹ lórí ayélujára àti SMS
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
- Ilé ẹjọ́ gba béèlì Baba Ijesha N2Miliọ̀nù ní wọ́n fún
- Kó sí ààyé fún ìdíbò ''Referendum'' nínú Ìwé Òfin Naijiria, dídádúró ilẹ̀ Yoruba Nation yóò nira- Amòfin
- Gọngọ́ sọ, àwọn Ṣọ́jà lé ọlọ́pàá lùgbẹ́ lágọ́ ọlọ́pàá l' Osogbo
Kó sí ààyé fún ìdíbò ''Referendum'' nínú Ìwé Òfin Naijiria, dídádúró ilẹ̀ Yoruba Nation yóò nira- Amòfin
Agbẹjọro lorilẹede Naijiria, Akeem Fadun ti fesi si ọrọ ti adari Ilana Ọmọ Oodua, Banji Akintoye sọ lori ipe fun awọn ọmọ Yoruba lati daduro kuro lara orilẹede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Agbẹjọro Fadun lasiko to n ba BBC sọrọ ni ko si ohun to jọ idibo ''refereendum ninu iwe ofin Naijiria nitori naa yoo lera fun awọn ẹya kan lorilẹede Naijiria lati bere fun idibo lati yapa kuro ni Naijiria.
O ni ohun akọkọ ti yoo kọkọ waye ni atunṣe si iwe ofin Naijiria lati fi aye gba idibo referendum fun awọn eniyan to ba fẹ yapa kuro ni ara Naijiria ati igba ti wọn yoo nilo lati gbe iru igbeṣẹ bẹẹ.
- Baba Ijesha yóò tún farahàn nílé ẹjọ́ mìí lónìí lórí ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọdé lòpọ̀
- Kwara Waka: Orin Wákà la fi ń ṣe Wáàsí, o tó ọdún 70 tí mo tí bẹ̀rẹ̀ láìnáání èébú tí ọ̀pọ̀ ń bú wa- Alhaja Rukayat Batimoluwasi
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo àti àwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ láti fí opin sí ìṣoro ètò aàbò
- Buhari ní kí ilé aṣòfin àgbà buwọ́lu N895b gẹ́gẹ́ bíi àfikún owó ètò ìṣúná ọdún 2021
Ninu ọrọ rẹ, agbẹjoro Fadun ni yoo nira fun awọn araalu lati dide sọ wi pe awọn fẹ idibo lati yapa kuro ni Naijiria lai si iranwọ gbogbo awọn gomina, asofin ati ṣẹnetọ ti wọn dibo yan.
''Awọn gomina, asofin, sẹnetọ ti wọn dibo yan ni Naijiria nikan lo ni anfaani lati fi ẹnu ko sọ fun ijọba wi pe awọn eniyan wọn ti ṣetan lati yapa kuro lorilẹede Naijiria,
Amofin naa ni: awọn araalu ko laṣẹ rẹ nitori ko si ninu ofin Naijiria.''
''Amọ ibeere nipe ṣe awọn eniyan ni ilẹ Yoruba paapaa awọn alaṣẹ ti awọn eniyan dibo yan sipo ti panugbọ lati sọ wi pe awọn fẹ yapa kuro ni Naijiria.''
''Ti ko ba si ajoyepọ laarin awọn ti wọn dibo yan ni iha Guusu orilẹede Naijria, ko le e ṣi aye fun referendum''
Amọ, agbẹjọro Akeem Fadun tun fikun pe ijọba laṣẹ lati kọ ijijagbara lati da duro nitori ko si ninu iwe ofin ti wọn yoo si pe wọn ni ẹgbẹ agbesunmọmi.
Fadun ni imọran ohun ni wi pe ki awọn ti wọn dibo yan gẹgẹ bi olori ni ilẹ Yoruba bere fun atunṣe si iwe ofin Naijiria ko le e fi aye gba idibo ''referendum'' ki awọn ẹya to ba fẹ kuro tabi yapa kuro ni Naijiria le ri ọna ati lọ lai da rogbodiyan silẹ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, others
Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ múra láti dìbò ''referendum'' kúrò ní Naijiria, ìjọ̀ba àpapọ̀ à ń bò- Banji Akintoye
Ọjọgbọn ati adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Banji Akintoye ti kesi awọn ọmọ Yoruba lapapọ lati gbaradi fun idibo ''bẹẹni'' abi ''bẹẹkọ'' lori ipe fun Yoruba Nation.
Akintoye sọ ọrọ yii ninu atẹjade ti wọn fi sọwọ si awọn oniroyin pẹlu atilẹyin oṣiṣẹ eto iroyin rẹ, Maxwell Adeleye.
O salaye wi pe idibo naa kii ṣe fun oloṣelu to n dibo, amọ fun awọn eniyan lati sọ wi pe awọn faramọ ki ilẹ Yoruba daduro abi ki wọn duro si ara orilẹede Naijiria.
Ọjọgbọn Akintoye jẹ ọkan lara awọn aṣofin agba lorilẹede Naijiria lasiko ijọba tiwantiwa keji ni Naijiria, iyen Second Republic.
Akintoye fikun un wi pe idibo naa yoo ran awọn eniyan lọwọ lati le gba ominira lọwọ ijọba Naijiria ati awọn Ajọ orilẹede lagbaye.
Akintoye ni: ''Awọn ọmọ Yoruba gbọdọ tẹsiwaju nipa ibeere fun ilẹ Yoruba nipa idibo bẹẹni abi bẹẹkọ, ti awọn eniyan yoo si lọ si ojuko idibo lati dibo boya wọn faramọ abi wọn ko faramọ.''
''Ohun ti wọn yoo kọ sibẹ ni pe, mo ṣetan lati kuro ni Naijiria, bẹẹni abi bẹẹkọ.''
Amọ Banji Akintoye ni awọn Yoruba gbọdọ fi imọ ṣọkan lori ibeere wọn, ki ohun wọn si lọ soke daradara ki gbogbo aye gbọ wi pe wọn ti ṣetan lati kuro lara orilẹede Naijiria.
- Wo àwọn ìlànà tí ó máa tẹ̀lé láti wo èsì ìdánwò 2021 Jamb UTME rẹ lórí ayélujára àti SMS
- Ẹ̀bùn owó, oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ìkókó mú wọlè fún ẹbí Kemisola Ogunniyi ní Ondo
- 'Òògùn ìtọ́jú egbò ni Musa pe àgbo tó fún mi, àmọ́ èèyàn mẹ́wàá ti kú lẹ́yìn tí wọ́n lò ó'
- Yinka Alaṣeyori fi ọ̀rọ̀ ìjínlẹ̀ púpọ̀ àti omijé ṣàlàyé Oniduro Mi
- Èèmọ́! agbébọn jí Olóyè Tafa àti ìyàwó rẹ́ gbé nílu Ibadan
''Ọna lati ṣe eyi ni lati polongo kaakiri ilẹ Yoruba, ti awọn eniyan si buwọlu u pe awọn fẹ kuro ni Naijiria.''
Akintoye rọ ẹgbẹgbẹrun miliọnu awọn ọmọ Naijiria nile ati ni oko lati buwolu idibo fun orilẹ-ede Yoruba, ki o ba le ṣeeṣe lati bere fun idibo ' referendum' lati kuro ni Naijiria pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ajọ lagbaye.

















