Ibadan Chief kidnap: Báyìí nì géńdé agbébọn ṣé na'wọ gán Olóyè Tafa àti ìyàwó rẹ́ lásìkò wẹli-wẹli òjò

Aworan agbebọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn agbebọn tẹnikan ko mọ ti gbe Baalẹ kan ati aya rẹ nilu Ararọmi to n bẹ ni agbegbe Bakatari nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Iroyin sọ wi pe awọn agbebọn naa yawọ ilu Ararọmi ni Bakatari lalẹ ọjọ Iṣẹgun wọn si gbe Baalẹ, Oloye Tafa Apanpa ati aya rẹ lọ.

Bakatari ti o jẹ ọkan lara awọn ilu to n bẹ ni ijọba ibilẹ Ido wa ni opopona marosẹ Ibadan si Abẹokuta.

Bakan naa lo jẹ ilu to paala laarin ipinlẹ Ogun ati Ọyọ.

Alaye ti awọn olugbe agbegbe naa ṣe ni pe ijinigbe Baalẹ ati aya rẹ waye lalẹ l'ọjọ Iṣẹgun ninu wẹliwẹli ojo to rọ n'Ibadan.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Bakan naa ni wọn fi kun ọrọ wọn wi pe ko si ẹni to mọ ibi ti Oloye naa ati aya rẹ wa titi di asiko yii.

Àkọlé fídíò, Kò sí ẹni tí mo fura sí lórí ikú ọkọ mi, àmọ́..- Adebisi aya Titus Ejanla tí wọ́n pa ní Ib

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Osifeso fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.

O ni awọn agbofinro ti bẹrẹ iṣẹ iwadi lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Fulani attack, Ajowa Ondo: Àwọn Bororo yìí ti kọ́kọ́ ń dàná ní Ajọwa tẹ́lẹ̀, ọmọ mi 5 di