Security: Ọba Okemesi ní ọwọ́ yẹpẹrẹ tọ́mọ Yorùbá fi mú àṣà ló jẹ́ kí àwọn ajínigbé máa gbé ọba láàfin

Oríṣun àwòrán, okemesi Ekiti
Bi ẹ ba ri ọba ilẹ Yoruba ti awọn agbebọn n ji gbe tabi pa, iru ọba bẹẹ ko bọwọ fun iṣẹṣe ilẹ Ooodua ni.
Owa Ooye ti ilu Okemesi Ekiti Oba Gbadebo Adedeji lo sọ eyi nigba to fi n tẹpẹlẹ mọ lilo awọn nkan amusagbara isẹnbaye Yoruba lati koju ipenija aabo to n koju Naijiria.
Owa Ooye ti ilu Okemesi Ekiti ni iru awọn nkan amuyẹ wọn yi le koju ijinigbe ati awọn iwa ọdaran mii to gbogo lawujo.
- Ọba Tejuosho tẹ ojú lọ́balọ́ba mọ́lẹ̀ fún ṣíṣe jìbìtì ìfẹ́ orí ayélujára - Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ
- A mú olódodo lọ́ ṣáájú ọjọ́ ibi - Leke Adeboye kọ lẹ́yìn ìròyìn pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Dare Adeboye jáde láyé
- Ọjọ́ 30 ni wọ́n fẹ́ fi gbé mi pamọ́, ariwo ọmọ ìjọ ló jẹ́ kí wọ́n tú mi sílẹ̀ - Father Mbaka
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ saaju ifilọlẹ eto ajọdun asa Okemesi Cultural Festival tọdun yi ni ọba naa salaye pe kani awọn ọba alade ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu asa wọn ni, awọn ajinigbe ko ba ma ribi maa nawọ gan wọn laafin wọn.
O ni bi wọn ba lo awọn nkan amusagbara yi bo ti se yẹ ni, ko le si ajinigbe tabi awọn janduku kankan to le se ikọlu si wọn tabi agbegbe wọn.
Oowa Oye naa ni lawọn orileede mii, asa jẹ ohun amuyangan ti awọn eeyan fi n pa owo wọle sugbọn , ọrọ ko ri bẹ ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, PAlace of the ooni of ife
''Ikọlu tawọn agbebọn n se si ori ade ti n peleke lẹnu ọjọ mẹta yi.Bawo lawọn janduku yoo ti se maa se ikọlu sawọn Kabiyesi ti wọn yoo maa pa wọn bi ẹni pa adiẹ?''
''Mo ni igbagbọ pe bi a ba fi ẹsẹ ile tọ ọrọ yi, gbogbo rẹ ni yoo niyanju''.
Kabiyesi tẹsiwaju pe laye atijọ ti awọn eeyan maa n kogun ja ara wọn, o ni bi awọn Yoruba se n jagun.
O ni ''awọn eeyan kan ko ni igbagbọ si isẹsẹ wa mọ nitori awọn ẹsin tuntun to yẹpẹrẹ agbara awọn babanla wa''
Koda o ni awọn Kabiyesi kan a maa sọ pe awọn ko le se irọra lati fi daabo bo ara wọn.
O ni iwa yi jẹ iwa ti ko bojumu.

Oríṣun àwòrán, PAlace of the ooni of ife
''Awa ni olusọ asa wa, a kii se ẹni to n fi asa wa rare nilẹ.Ki lo de ta fi n sa kuro nidi asa wa?''
Lẹnu ọjọ mẹta yi ni ilẹ Yoruba ati lawọn aaye miran ni Naijiria, ijingbe paapa tawọn oriade ko jẹ nkan tuntun mọ.
Ni ipinlẹ Ekiti, awọn ajinigbe ti se ikọlu sawọn ọba kan ti wọn si ti ji awọn kan pe to fi mọ awọn mii to padanu ẹmi wọn lọwọ awọn olubi wọn yi.
Pupọ araalu lo ti n kesi ijọba lati wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ yi nitori inu ibẹrubojo lawọn araalu ati awọn lọbalọba naa n gbe.
















