Romance Scam: Ìdí rèé tí ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ilẹ̀ Egba fi ní kí Olóyè Tejuosho lọ rọọ́kún nílé

Oba Tejuosho

Oríṣun àwòrán, HRH Oba Tejuosho

Igbimọ lọbalọba Kemta nilẹ Egba ti kede pe awọn ko lohun kankan se pẹlu ọba Adetokunbo Tejuosho ti wọn fẹsun kan pe o lu awọn eeyan ni gbajuẹ lori ọrọ fifẹ ara ẹni.

Ninu atẹjade kan ni wọn ti fi to awọn akọroyin Naijiria leti lẹyin ipade wọn to waye ni Ile Ogboni Kemta.

Awọn to buwọlu iwe ipinnu awọn lọbalọba yi ni Oloye Yomi Rotimi, Oluwo Kemta, Oloye Oluwatosin Fadare(Lukotun Kemta) ati Oloye Bola Taiwo(Sakotun Kemta).

Wọn ni ẹsun yi to fi mọ bi awọn ọlọpaa se mu oriade yi jẹ nkan to doju ti gbogbo ilu ti wọn si fi kun pe Adetokunbo Tejuosho ko yẹ lẹni a yan sipo olori ilu.

Àkọlé fídíò, '500 level'' ni mo wà nígbà tí mo di adélé Ọba'

Yatọ si eleyi, wọn tu isu de isalẹ koko pe ọna ẹburu ni Oloye Tejuosho gba lati de ipo Olu ilu Kemta.

Ninu alaye wọn, wọn sọ pe oye baalẹ Adebonyin ni Orile Kemta ijọba ibilẹ Odeda ni o kọkọ jẹ.

Lẹyin igba naa ni ijọba ana nipinlẹ Ogun yan si ipo Olu ilu Kemta lai fi tawọn igbimọ lọbalọba se tabi iyọnda Alake ilẹ Egba Oba Adedotun Aremu Gbadebo.

Wọn ni ijọba ori oye yi sagbeyẹwo iyansipo awọn Ọba marundinlọgọrin kan ti igbimọ si ni ki wọn ja ipo wọn silẹ di baalẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

Asẹyinwa asẹyinbọ awọn ọba tọr kan gbe ẹjọ lọ sile ẹjọ ti wọn si sọ pe adajọ ni ki wọn si yi wa lori ipo baalẹ ti ijọba ni ki wọn wa.

Awọn igbimọ lọbalọba sọ pe o seni laanu pe Oloye Adetokunbo si n pe ara rẹ lọba toun ti pe ijọba ti rọọ looye di baalẹ.

Lakotan igbimọ yi wa tori ẹsun ti wọn fi kan Oloye Tejuosho lọjọ Kejidinlọgbọn Osu yi ni ko lọ rọọkun nile tori naa ko yẹ ni ipo Baalẹ tabi Olu ilu Kemta.

Titi di baa se n ko iroyin yi jọ, a ko ti ribi gbọ ọrọ lẹnu Oloye Tejuosho lori igbesẹ igbimọ lọbalọba to ni awọn ko fẹ ni ipo baalẹ tabi Olu ilu Kemta.