Ọba Abdulrasheed Akanbi rọ àwọn Ọba aláde yoruba láti dẹ́kun ẹgbẹ́ òkùnkùn síṣe

Oba Abdulrasheed Akanbi

Oríṣun àwòrán, emprotelu1

Àkọlé àwòrán, Ọba Abdulrasheed Akanbi rọ àwọn ọba aláde yoruba láti dẹ́kun ẹgbẹ́ okunkun síṣe

Olúwo ti ìlú Iwo Oba Abdulrasheed Akanbi ti ké si àwọn Ọba aládé ní gbogbo ilẹ̀ Káàrọ oò-jííre láti kúrò nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn ti wọ́n ń ṣe.

Olúwo ni gbogbo àwọn ẹgbẹ́ báwọnyìí máa ń sọ wọ́n di ẹrú ni nígbá ti wọ́n ba jẹ́jẹ̀ẹ́ owó àtí àwọn agbára ẹmi àìrí.

Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nínú àtẹjade kan to fi síta láti ọwọ́ akọwé rẹ̀ Alli Ibraheem, Oba Abdulrasheed ní okiki wọ́n ti dínku nípa àwọn ẹgbẹ́ ti wọ́n ń ṣe.

O ní ọ̀pọ̀ Ọba ní ìhà ìwọ̀ -òòrun -Guusu ní láti dári jọ ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ ti yóò dá ògo Yorùba àti àṣẹ ti Ọlọrun fún wọ́n pada gẹgẹ bii Ọba.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Imam Fuad tako Oluwo lori wiwe lawani
Àkọlé fọ́nrán ohùn, Oluwo Ìwo ṣ'àlàye lori oyé oba oni lawàni

Ọba Akanbi ké si Alaafin Oyo, Oba Lamidi àti Awujale ti Ijebu Oba Sikiru láti sááju ìjàgbara kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ okunkun.

O ní " Àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ti gbá gbogbo ẹtọ Ọba. Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà ní pe kí àwọn asáájú ọba jìjàgbara. Mo ri Alaafin àti Awùjalẹ̀ gẹ́gẹ àwọn tí wọ́n ni ìgboyà. Baba Alaafin lé sááju ìpolongo pẹ̀lú Awujale, wọn mọ ìtàn."

Àkọlé fídíò, Èmi ni Awùjalẹ̀ ti Iwo
Àkọlé fídíò, 'Buhari, Saraki, Dangote, abẹ́ mi ni wọ́n wà'