9th Assembly: Femi Gbajabiamila ni ẹgbẹ́ APC fọwọ́sí sùgbọ́n...

Bago àti Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @femigbaja, @HonBago

Àkọlé àwòrán, Bago àti Gbajabiamila

O kéré tan ènìyàn mẹ́ẹ̀dógún ló bẹ̀rẹ̀ eré ìje láti di agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ àṣojú-ṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gba ipò Yakubu Dogara to jẹ ẹ́ ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfín ti ẹlẹ́kẹjọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn mííràn ò kéde síta nígbà ti àwọn mííràn ni àwọn ń ba àwọn akẹgbẹ́ àwọn sọ̀rọ̀ lábẹ́lẹ̀. Femi Gbajabiamila, olùranlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ lọ́rí ọ̀rọ̀ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Abdulrahman Sumaila, Ahmed Wase Muhammed Monguno àti àwọn míì.

Ní báyìí, awọn ẹgbẹ́ amúṣẹyá ẹgbẹ òṣèlú PDP ní àwọn ti fọ́wọ́ sí láti dibò yan Ali Ndume gẹ́gk bii ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin nígbà ti wọ́n fọwọ si Umar Mohammed Bago gẹ́gẹ́ agbẹ́nusọ ilé ìgbìmọ aṣojú-ṣòfin.

Eyí ní ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níní àtẹjáde kan tí wọn fi sita ní ààgo kan àbọ owúrọ oni tí àkọwé àpapọ̀ ẹgbẹ́ sẹnatọ Umar Ibrahim Tsauri sí fọwọ́ sí

Àkọlé fídíò, 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

Àwọn to ti jẹ Agbẹnusọ láti ọdún 1999

Salisu Buhari 1999-2000 PDP Iwọ-òòrun -Arewa

Ghali Umar Na'Abba 2000-2003 Iwọ-òòrun -Arewa

Aminu Bello Masari 2003-2007 Ìwọ-òòrun -Arewa

Patricai Etteh 2007 Iwọ-òòrun -Guusu

Dimeji Bankole 2007-2011 Iwọ-òòrun- Guusu

Aminu Waziri Tambuwal 2011-2015 wọ-òòrun -Arewa

Yakubu Dogara 2015-2019 Ila-òòrun Arewa

Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Àwọn tó ń dupo agbénusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí pín ipò agbẹnusọ sí ìwọ̀-òòrun -Guusu tí wọ́n sì yan asoju ọmọ ilé to pọ jù lọ, Femi Gbajabiamila gẹgẹ́ bi ẹni tí wọ́n fọ́wọ́ sí nígbà ti wọ́n pín ìgbá keji sí gbùngbùn Ariwa.

Ṣùgbọ́n o, ìdìde Umar Mohammed Bago láti ìpínlẹ̀ Niger àti John Dyegh láti ìpinlẹ̀ Benue.

Mohammed Bago ti dide pe àṣìṣe ńlá ni ẹgbẹ́ APC ṣe láti pín ipò agbẹnusọ sí ìhà iwọ oorun Guusu nítori náà oun kò fara mọ ọ àti pé ìhà gbungbu Arewa kò ti de ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ aṣoju sofin ri, nítori náà òun náà yóò dije fún ipò Agbẹnusọ

Muhammed nínú àtẹjade kan sàlàyé pé iha Ila-òòrun-Gusu àti Gbungbun -Arewa ní ẹgbẹ ń fiya pínpín wọn jẹ jùlọ

Ní báyìí, ìdìbò tí yóò wáye ní òní ọjọ kọkanlá oṣù kẹfà ódún 2019 ń pè kí Gbajabiamila kò ni ẹtọ láti lọ nítori ó yẹ ki àwọn àṣojú ẹgbẹ́ ó tún ètò náà ṣe.

Àkọlé fídíò, Olusegun Obasanjo: Ọmú ìyá mi ti mo fi ń mùkọ ni kekere ló jẹ ki ń lókun

Ìdìbò ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-sòfin fún sáà 2015-2019

Ẹwẹ̀, lòdì si ìpínu ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní sáà tó kọja ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC kan pàdí àpò pọ pẹlú ẹgbẹ́ alátako láti gbé Bukola Saraki wolé gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àti Yakubu Dogara wolé gẹ́gẹ́ bi aggbẹ́nusọ ilé aṣojú-ṣòfin.

Ní bayìí aṣoju ọmọ ile to kéré jùlọ nígbà kan rí George Akime ti rọ gbogbo ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin àgbà àti aṣojú-ṣòfin láti ri dáju pe wọn bọ̀wọ̀ fún ipinu ẹgbẹ́ láti dibò fún Ahmed Lawan gẹ́gẹ́ bi ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin àti Femi Gbajabiamila bi agbẹ́nusọ aṣoju-ṣòfin kí ǹkan tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún mẹ́rin sẹyìn máà tún wáye.