9th Assembly: Olùdíje mẹ́rin ṣàtìlẹyìn fún Gbajabiamila ṣáájú ìbò ilé aṣojú ṣòfin

Femi Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, @femigbaja

Àkọlé àwòrán, Femi Gbajabiamila

Bi idibo adari ile igbimọ aṣoju ṣofin l'Abuja ti wọle de, awọn oludije mẹrin ọtọọtọ lo ti sọ pe awọn ko ni dupo naa mọ, ti wọn ṣeleri lati ṣatilẹyin fun Femi Gbajabiamila.

Aṣoju ṣofin Gbajabiamila gan ni ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress(APC) fọwọ sii pe ko jẹ adari ile aṣoju ṣofin l'Abuja.

Ọkan gboogi lara awọn oludije naa, Nkeiruka Onyejiocha lo kọkọ kede atilẹyin rẹ fun Gbajabiamila.

Dokita Jibrin Abdulmumini to jẹ oludari ipolongo ibo fun Gbajabianmila lo fọrọ naa lede lẹyin ipade to waye laarin awọn alatilẹyin Gbajabiamila ati oun funra rẹ l'Abuja.

Awọn oludije miiran to tun ṣeleri atilẹyin wọn fun Gbajabiamila ni Buba Yakubu, Aliyu Betara, ati Abdulrazak Namdas.

Aṣoju ṣofin Abdulmumini fikun ọrọ rẹ pe Gbajabiamila lawọn ọmọ ile igbimọ aṣoju ṣofin lati iwọ oorun gusu naa fẹdibo fun un.

Àkọlé fídíò, Ladoja: Àwọn èèyàn Oyo fì ìbò sọ̀rọ̀ pé ìjọba Ajimobi kò dára
Àkọlé fídíò, Iba Gani Adams: Bẹ́ẹ gbé màláíkà kan lọ sí Aso Rock, kò lè ṣàṣeyọrí

Amọ, John Dyegh to n ṣoju ẹkun Gboko/Tarka nipinlẹ Benue to si tun jẹ ọmọ ẹgbẹ osẹlu APC loun si wa maa dije fun ipo adari ile igbimọ aṣoju ṣofin.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa ni ibo naa yoo waye niluu Abuja.